Home ÀKỌ̀TUN Ọkọ le ìyàwó jáde tọmọ-tọmọ nítorí àwọ̀ tí ojú àwọn ọmọ ní
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - August 4, 2020

Ọkọ le ìyàwó jáde tọmọ-tọmọ nítorí àwọ̀ tí ojú àwọn ọmọ ní

Ọkọ le ìyàwó jáde tọmọ-tọmọ nítorí àwọ̀ tí ojú àwọn ọmọ ní

Fẹ́mi Akínṣọlá

Bí ìran tiwa yìí ṣé gbà pé oore ńlá ní ọmọ bíbí jẹ́, bẹ́ẹ̀ náà ni wọn tún kà á kún ẹ̀bùn pàtàkì láti ọ̀dọ̀ Elédùwà.
Ó wá ṣeni ní kàyééfì pé bàbá kan ti dijú kọ àwọn ẹ̀bùn yìí sọ́rùn ìyá tó bí wọn fún un .

Bàbá àwọn ọlọ́mọ méjì ọ̀hún la gbọ́ pé ó lé ìyàwó rẹ̀ àti ọmọ rẹ̀ méjèèjì jáde nílé nílùú Ilorin, nítorí àwọ̀ tí ojú àwọn ọmọ náà ní.

Arábìnrin kan tó mọ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà, Alabi Rukayat Oyindamola, ló kọ́kọ́ gbé Ìròyìn nípa rẹ̀ sí orí ayélujára Facebook.

Arábìnrin Moromoke sọ fún akọròyìn pé, àwọn ẹbí ọkọ òun ló kó ọ̀rọ̀ sí ọkọ lórí láti gbé ìgbésẹ̀ tó gbé.

“Wọ́n sọ fún ọkọ ò mi pé, ṣé bí gbogbo ọmọ tí màá bí yóó ṣe má a ri nìyí?”

O tẹ̀siwaju láti sọ pé àkọ́bí ọmọ òun, Kaosara jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́jọ, tí èyí àbúrò, Hassanat sì jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rin ààbọ̀.

Arábìnrin Moromoke tẹ̀síwájú pé láti ìgbà tí wàhálà yìí ti bẹ̀rẹ̀ ni ọkọ òun kò ti fi owó sílẹ̀ fún oúnjẹ tàbí ìtọ́jú Ilé sílẹ̀ mọ́.

“Èmi náà ní irú àwọ̀ ojú yìí. Èmi nìkan ni mo sì ní irú rẹ̀ nínú ẹbí wa. Nítorí náà, kò jẹ́ ìyàlẹ́nu pé mo ń bí àwọn ọmọ tó ní i.
Kódà, àyẹ̀wò oríṣìríṣi ni wọ́n ṣe fún ọmọ mi kejì nígbà tí mo bí i síléèwòsàn nítorí ojú náà, ṣùgbọ́n wọn kò rí àìsàn kankan lára rẹ̀.”

Ó fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé àwọn òbí òun ránṣẹ́ pe ẹbí ọkọ òun láti yanjú ọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni nínú wọn kò yọjú.

Ní báyìí, Arábìnrin náà sọ pé ilé àwọn òbí òun ni òun padà sí láti má a gbé, láti ìgbà tí ọkọ ti lé e jáde tọmọtọmọ.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Okorocha ketí ikún sí ìpé làwọn fi ṣígun kàá mọ́lé mọ́lé-EFCC

Wọ́n ní Okorocha ketí ikún sí ìpé làwọn fi ṣígun kàá mọ́lé mọ́lé Ọrẹ Òtítọ́jù Àjọ tó ń gbó…