Home ÀKỌ̀TUN Káńbààdì àti afẹ́fẹ́ gáàsì ló fa ìbúgbàmù ọ̀hún-LASEMA
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - July 31, 2020

Káńbààdì àti afẹ́fẹ́ gáàsì ló fa ìbúgbàmù ọ̀hún-LASEMA

Káńbààdì àti afẹ́fẹ́ gáàsì ló fa ìbúgbàmù ọ̀hún-LASEMA

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ọ̀rọ̀ ìbúgbàmù tó ń fojoojúmọ́ wáyé nípìńlẹ̀ Èkó báyìí ti wá di Àìláṣọ lọ́rùn pààká báyìí, èyí tó tó àpérò fún gbogbo Maríwo.

Ìdí ni pé ìṣẹ̀lẹ̀ ìbúgbàmù míràn tún ti wáyé nílù Èkó lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun nínú ibùdó ìtajà kan tí wọ́n ti ń ta afẹ́fẹ́ gáàsì àti èròjà Káńbààdì.

Àjọ tó ń rí sí àkóso ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì nípìńlẹ̀ Èkó, LASEMA tó fìdí rẹ̀ múlẹ̀ lójú òpó abẹ́yefò Twitter rẹ̀, sàlàyé pé òpópónà Afáríogun ládùgbóò Ajao Estate nílùú Èkó ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé.
Lasema ní ìbúgbàmù Káńbààdì àti afẹ́fẹ́ gáàsì papọ̀ yìí sì ló ṣokùnfà ìjàǹbá iná alágbára kan nínú ilé ìtajà náà.

Ó kéré tán Iléeṣẹ́ bíi , mẹ́sàn míràn ló fara gbá nínú ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún ibùdó ìtajà níbẹ̀ , tí wọ́n sì jóná kanlẹ̀.

Iléeṣẹ́ tó ń se àkóso àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì nípìńlẹ̀ Èkó ní ìfọwọ́sowọ́pọ̀ iṣẹ́ Àjọ panápaná nípìńlẹ̀ Èkó àti Àjọ náà ló mú kí wọ́n tètè bu omi pa ìjàǹbá iná náà.

Ọ̀pọ̀ èròjà bíi ọ̀pá, sìlíńdà gáàsì àti àwọn nǹkan míràn tó ti jóná ni wọ́n rí níbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà, tí Àjọ Lasema kò sì sọ bóyá ẹ̀mí kankan sọnù nínú ìjàǹbá náà.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu

Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu Ọrẹ Òtítọ́jù Olùdíje fún i…