Home ÀKỌ̀TUN O̩wó̩ te̩ àwo̩n aláseju agbófinro tó yè̩yé̩ o̩ló̩mo̩ge kan
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - July 25, 2020

O̩wó̩ te̩ àwo̩n aláseju agbófinro tó yè̩yé̩ o̩ló̩mo̩ge kan

O̩wó̩ te̩ àwo̩n aláseju agbófinro tó yè̩yé̩ o̩ló̩mo̩ge kan

Yínká Àlàbí

Owo awon olopaa ti te awon agbofinro to yeye olomoge to pari Yunifasi re ni Ibadan
Yoruba bo, won ni ” amuni n je amuni, ewo ni o o ni bo ninu re”.
Awon agbofinro kan ni won se ise akoni lati mu odaran kan ti o ti n sa mo won lowo fun igba die. Bi won se ka afunra si odaran na mo ile kan ti o sa pamo si pelu orebinrin re.
Won ba bere si ni bi okunrin naa ni orisiirisii ibeere lati gbe ara won ga pe ” bi odaran ba wo inu iho ile, owo awon maa tee”.
Loju gbogbo eniyan, won gba pe ko si ohun to buru ninu re sugbon nigba ti o di ti orebinein re ni won ba gbogbo ise akoni won je. Won bere si ni bi obinrin naa ni awon ibeere ifini seleya pe “igba wo ni won jabale re? Se won baa lajosepo moju ati bee bee lo.
Won se gbogbo eleyii, won wa juu si ori ero ayelujara, se Yoruba bo, won ni ” ibere ija laa mo, ko se ni to mo ipari re”. Oro ti beyin yo fun awon agbofinro naa gege bi alukoro awon olopaa, alagba Frank Mba se salaye fun awon oniroyin.
Awon ti owo te naa ni ASP Tijani Olatunji,Inspector Gboyega Oyeniyi,Corporal Aiyedun Akeem ati Ope Owoeye. Ase lati fi owo sinkun ofin mu awon agbofinro yii wa lati odo oga olopaa patapata Ogbeni Mohammed Adamu. Iwadii to gbopan si n lo lowo lori ohun ti awon agbofinro naa ri lobe ti won fi waro owo.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ilé ẹjọ́ tú el-zakzaky àti ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀

Ilé ẹjọ́ tú el-zakzaky àti ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀ Fẹ́mi Akínṣọlá Ajá tó relé ẹkùn tó bọ̀,ó tọ́ kí…