Home ÀKỌ̀TUN Àwọn mẹ́ta ti wà pẹ̀lú agbófinró lórí ikú Tolúlọpẹ́ Arótilé
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - July 25, 2020

Àwọn mẹ́ta ti wà pẹ̀lú agbófinró lórí ikú Tolúlọpẹ́ Arótilé

Àwọn mẹ́ta ti wà pẹ̀lú agbófinró lórí ikú Tolúlọpẹ́ Arótilé

Fẹ́mi Akínṣọlá

Kí Ọlọ́run ṣá má a kó wa yọ ni. Àwọn èèyàn kan wáyé wá lo ògo, nígbà tí àwọn èèyàn mìíràn tẹ̀lé wọn wáyé wá pa ògo ìràwọ̀ tó ń tàn.
À bí kínni ká ti pe tàwọn oní sábàbí aburú tó járàwọ̀ Tolúlopẹ́ Arótilé lójijì, bí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ abiyamọ ṣe ń tomijé lójú pòròpòrò bi wọ́n ṣe ń gbé màjèsìn ọmọ ogun ofurufu n-nì, Tolúlopẹ́ Arótilé wọ káà ilẹ̀ láé láé sùn lọ́jọ́bọ ní itẹ́ ìsìnkú àwọn akọni lójú ogun ní ìlú Àbújá.

Iléeṣẹ́ ọmọ ogun òfurufú ti fa àwọn mẹ́ta tó wà nínú ọkọ̀ tó pa Tolúlopẹ́ Arótilé lé àwọn agbófinró lọ́wọ́ báyìí.

Nínú àtẹjáde kan tí iléeṣẹ́ ọmọ ogun òfurufú fi síta báyìí ni wọ́n ti kéde pé ìgbésẹ̀ yìí di dandan lásìkò yìí.

Ọ̀gágun Ibikunle Daramola tó jẹ́ alukoro iléeṣẹ́ yìí ní Nehemiah Adejoh, Igbekele Folorunsho ati Festus Gbayegun ló wà nínú ọkọ̀ tí ó pa Tolúlopẹ́ Arótilé.

niIléeṣẹ́ ológun òfurufú tó wà ní Kàdúná, ni Ìbíkúnlé ti sọ̀rọ̀ yìí.

Ó ṣàlàyé ní kíkún lórí bí ìjàmbá ọkọ̀ náà ṣe wáyé nígbà tí ó ń fa àbájáde wọn lé Ọ̀gágun Hadi Ahmed tó jẹ́ Commander 453 Base Services Grioup (453 BSG) ní Kàdúná .
lọ́wọ́.

Lọjọ kẹrìnlá, oṣù keje ní ìrọ̀lẹ́ bíi aago mẹ́rin àbọ̀ ni ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú yìí ṣẹlẹ̀.

Ọkọ̀ Sìẹ́nà tó ní nọńbà ìdámọ̀ AZ 478 MKA (Kaduna) ni Adejoh wà, tó sì kọlu Tolúlopẹ́ lásìkò tó ń rìn ní òpópónà Air Marshal Ibrahim Alfa ní NAF Base ni Kaduna kó tó di pé ẹlẹ́mìí gbàá.

Ọ̀gágun àgbà náà ṣàlàyé pé àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tí wọ́n fà lé agbófinró lọ́wọ́ yìí jẹ́ àwọn tí Tolúlopẹ́ jọ lọ sílé ìwé girama ológun òfurufú ní Kàdúná “Air Force Secondary School Kaduna”.

Àti pé àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta fẹ́ lọ kí ìyàwó ọ̀ga wọn nínú ọgbà ológun náà ni lásìkò tí ìṣẹ̀lẹ̀ láabi náà ṣẹlẹ̀.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run Ọrẹ Òtítọ́jù Ayẹyẹ ọjọ́ọ̀bì à…