Home ÀKỌ̀TUN N-Power Batch A àti B tí kò tíì gba owó òṣù ti ríṣẹ́ sí ibòmíràn – ìjọba àpapọ̀
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - July 24, 2020

N-Power Batch A àti B tí kò tíì gba owó òṣù ti ríṣẹ́ sí ibòmíràn – ìjọba àpapọ̀

N-Power Batch A àti B tí kò tíì gba owó òṣù ti ríṣẹ́ sí ibòmíràn – ìjọba àpapọ̀

Fẹ́mi Akínṣọlá

N-Power jẹ́ ọ̀nà tí Ìjọba ń gbà pèsè iṣẹ́ fún àwọn ọ̀dọ́ , lábẹ́ ẹ̀ka Ìjọba tó ń rí sí ètò amúlùúdùn àti ìdẹ̀kùn sápá àwọn ará ìlú.

Ilé iṣẹ́ Ìjọba àpapọ̀ lórí amójútó ará ìlú, mímójútó àjálù ídàgbàsókè ètò amúlùúdùn ti sàlàyé pé ẹnikẹ́ni tí kò bá tíì gba àjẹmọ́nú tirẹ̀ túmọ̀ sí pé orúkọ ẹni bẹ́ẹ̀ wà ní ilé iṣẹ́ Ìjọba àpapọ̀ míràn ni.

Èyí ni ó jẹyọ nínú àtẹjáde ti ilé iṣẹ́ náà fi síta tí ìgbákejì adarí Ilé iṣẹ́ náà Rhoda Ishaku Iliya sì buwọ́lù lọ́jọ́bọ.

Ilé iṣẹ́ náà ní àwọn ti fi orúkọ àwọn ẹgbẹ̀rún tó lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta àwọn tó wà lábẹ́ ètò N- Power ṣọwọ́ sí ọ́fíísì akọ̀wé owó Ìjọba àti ti àwọn ẹgbẹ̀rún méjìlélẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta náà sì ti rí owó wọn láti orí ètò GIFMIS tí Ìjọba là sílẹ̀ láti máa fi san owó ọ̀hún.

Wọ́n fi kún pé àwọn bí ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlà tó kù tí kò rí owó gbà túmọ̀ sí pé orúkọ wọ́n padà ni, nítorí pé orúkọ wọn ti jẹyọ nílé iṣẹ́ Ìjọba àpapọ̀ míràn èyí sì lòdì sí òfin N-Power.

Mínísítà Ilé iṣẹ́ náà Sadidya Umar Farouq rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ ojúlówó N-Power tí kò tíì rí owó náà gbà láti fọwọ́ wọnú.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Rògbòdìyàn ẹgbẹ́ onímọ́tò Èkó n fẹ́jú kẹkẹ

Rògbòdìyàn ẹgbẹ́ onímọ́tò Èkó n fẹ́jú kẹkẹ Ọrẹ Òtítọ́jù Àwọn àgbà sọ pé ìjàngbọ̀n kìí nìka…