Home ÀKỌ̀TUN Ààrẹ Buhari lọ parí ìjà nílẹ̀ Mali
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - July 24, 2020

Ààrẹ Buhari lọ parí ìjà nílẹ̀ Mali

Ààrẹ Buhari lọ parí ìjà nílẹ̀ Mali

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ìwé mímọ́ ṣọ pé,olùbùkún fún ni onílàjà, torí pé , ọmọ Ọlọ́run ni a ó máa pè wọ́n.Ó jọ pé àmúṣẹ ọ̀rọ̀ yìí náà ni Ààrẹ Orílẹ̀ yìí Muhammad Buhari tẹ̀ lé tó fí tẹkọ̀ létí re orílẹ̀-èdè Mali.

Níṣe ni Ààrẹ Buhari dé Mali tó wọ ìbòmú fún ìgbà àkọ́kọ́ n’íta gbangba ní olú ìlú Orílẹ̀-èdè Mali lọ́sàn ọjọ́bọ ní ìrìnàjò ọlọ́jọ́ kan tó lọ fún ìjíròrò.

Ìbẹ̀wò Ààrẹ Buhari yìí dá lóríi ìfọ̀rọ̀wérọ̀ pẹ̀lú Ààrẹ àná l’Órílẹ̀ yìí , Goodluck Jonathan tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn abánijíròrò fún àjọ ECOWAS tó lọ sí orílẹ̀-èdè Mali láti lọ yanjú ọ̀rọ̀.

Ààrẹ àná, Jonathan ló ṣẹ̀sẹ̀ gba iṣẹ́ àkànṣe tí àjọ ECOWAS, ọ̀hún àti Ààrẹ orílẹ̀-èdè Niger Republic, Mahamadou Issoufou ti pohùn pọ̀ láti pàdé ní Mali fún ìjíròrò láti yanjú aáwọ̀ tó wà láàrin Ààrẹ orílẹ̀-èdè Mali, Boubacar Keita àti alátakò rẹ̀.

Garba Shehu tó jẹ́ olùrànlọ́wọ́ pàtàkì fún Ààrẹ Buhari sọ fún akọròyìn pé àwọn adarí orílẹ̀-èdè lájọ ECOWAS fẹ́ lọ ní ọ̀rọ̀ pẹ̀lú ìhà ti Mali nínú aáwọ̀ náà lẹ́yìn tí ikọ̀ ti Ààrẹ Buhari rán lọ, ìyẹn, Goodluck Jonathan tí í ṣe Ààrẹ àná kò rí ojútùú sí aáwọ̀ náà.

Ó ní wíwà níbẹ̀ àwọn adarí yìí leè sèrànwọ́ láti yanjú ọ̀rọ̀ tó wà nílẹ̀ – “bóyá ipò wọn gẹ́gẹ́ bíi adarí nílẹ̀ Áfírìkà leè mú kí wọ́n gbọ́rọ̀ sí wọn lẹ́nu, kí àlàáfíà sì jọba ní Mali.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run Ọrẹ Òtítọ́jù Ayẹyẹ ọjọ́ọ̀bì à…