Home ÀKỌ̀TUN Eyitayo Jegede jáwé olúborí láti díje du ipò gómìnà fún PDP
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - July 23, 2020

Eyitayo Jegede jáwé olúborí láti díje du ipò gómìnà fún PDP

Oṣù kẹwàá ọdún yìí ni INEC yóó ṣètò ìdìbò míì ní ìpínlẹ̀ Òǹdó

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ni ìgbẹ̀yìn ohun gbogbo nínú ẹgbẹ́ òṣèlú alábùradà PDP ní ìpínlẹ̀ Òǹdó. Àbájáde wọn tí wà lórí àtẹ báyìí.

Ní ọjọ́ kejìlélógún, oṣù keje 22/7/2020 ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ ètò ìdìbò náà níbi tí àwọn Olùdíje mẹ́jọ ti pàdé wàákò láti mọ ẹni tí yóó ṣojú ẹgbẹ́ òṣèlú “Peoples Democratic Party” nínú ìdìbò tó ń bọ̀.

Lóru mójú òní, ọjọ́ kẹtàlélógún, oṣù keje 23/7/2020,ni àwọn alámòjútó ìdìbò abẹ́lẹ̀ náà kéde àbájáde èsì ìdìbò ẹnì tó máa gba tíkẹ́ẹ̀tì PDP láti di Gómìnà Ìpínlẹ̀ Òǹdó.
Lẹ́yìn akitiyan níwá lẹ́yìn ni àwọn ìgbìmọ̀ kéde àwọn tó fífẹ hàn wọ̀nyí lẹ́sẹẹsẹ pẹ̀lú iye òǹkà ìbò wọn.
Eddy Olafeso – 175
Ajayi Agboola – 657
Banji Okunomo – 90
AyorindeOlabode-95
Boluwaji Kunlere -33
Ebiseni Olusola – 29
Erewa Godday – 14
Eyitayo Jegede -888

Lẹ́yìn tí wọ́n kéde èsì ìdìbò yìí ni wọ́n fa Eyitayo Jegẹde kalẹ̀ lórúkọ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP pé kó dìde gírí bí ọmọkùnrin láti kójú Arákùnrin APC àti àwọn aṣojú ẹgbẹ́ òṣèlú tó kù tí wọ́n jọ máa díje ìdìbò tó ń kànkùn gbọ̀ngbọ̀n náà

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu

Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu Ọrẹ Òtítọ́jù Olùdíje fún i…