Home ÀKỌ̀TUN Mò ń jókòó àlàáfíà pẹ̀lú àwọn olùdíje yókù fún ìtẹ̀síwájú– Akérédolú
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - July 22, 2020

Mò ń jókòó àlàáfíà pẹ̀lú àwọn olùdíje yókù fún ìtẹ̀síwájú– Akérédolú

Mò ń jókòó àlàáfíà pẹ̀lú àwọn olùdíje yókù fún ìtẹ̀síwájú– Akérédolú

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé àwọn àgbà bọ̀ wọ́n ní níse là á wá ọ̀rẹ́ kún ọ̀rẹ́ , èèyàn tó bá fẹ́ láṣeyọrí, kìí fi ọ̀tẹ̀ wá ọ̀tá kún ọ̀tá, Nítorí pé igi tí a bá fojú rénà, níí gbéni ṣubú.

Èyí náà ló mú kí Gómìnà Ìpínlẹ̀ Òǹdó, Rótìmí Akérédolú sọ pé òun ti bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ àlàáfíà láàrin rẹ̀ àtàwọn akẹẹgbẹ́ rẹ̀ nínú ẹgbẹ́ òṣèlú APC ní ìpínlẹ̀ náà, kí nǹkan lè ṣẹnu re fún ẹgbẹ́ òṣèlú náà ní Ìpínlẹ̀ Òǹdó.
Akérédolú ló fi ọ̀rọ̀ náà léde fún akọròyìn.

Ó ni “Adúpẹ́ fún àṣeyọrí tí a rí nínú ìdìbò abẹ́lé tí a ṣe kọjá, ṣùgbọ́n oun tó wà níwájú wa ṣì ju ìṣẹ́gun tí a ti ní sẹ́yìn lọ.”

Gómìnà ọ̀hún ṣàlàyé pé ìfọwọ́sowọ́pọ̀ nìkan ló leè mú ìtẹ̀síwájú bá ẹgbẹ́ òṣèlú APC àti ìpínlẹ̀ Òǹdó, nítorí náà ni òun ṣe gbé ìgbésẹ̀ ọ̀hún, kí àlàáfíà leè jọba.

Ní báyìí, Akérédolú ti lọ sàbẹ̀wò sí àwọn tí wọ́n jọ díje nínú ìdìbò abẹ́lé náà, lára àwọn ni Olusola Oke, Salo Iji àti D.I Kekemeke.
Akérédolú ló jáwé olúborí nínú ìbò abẹ́lé tó wáyé nínú ẹgbẹ́ òṣèlú APC láti yan olùdíje sípò Gómìnà nínú ìdìbò ti yóó wáyé lóṣù Kẹwàá ọdún 2020.

Ṣaájú ìdìbò abẹ́lé náà ni oríṣìríṣi nǹkan tí n ṣẹlẹ̀ nínú ìṣèjọba Akérédolú, àkọ́kọ́ ni pé ìgbákejì rẹ̀, Agboola Ajayi fi ẹgbẹ́ APC sílẹ̀, tó sì lọ darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP.

Kò pẹ́ sí àsìkò ọ̀hún ni Akọ̀wé Ìjọba rẹ̀, Ifedayo Abegunde náà kọ ẹ̀yìn sí Akeredolu.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo Ọrẹ …