Home ÀKỌ̀TUN Họ́wù! Kò ṣeéṣe kí ogójì bílíọ́nù náírà sọnù–Akpabio
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - July 21, 2020

Họ́wù! Kò ṣeéṣe kí ogójì bílíọ́nù náírà sọnù–Akpabio

Họ́wù! Kò ṣeéṣe kí ogójì bílíọ́nù náírà sọnù–Akpabio

Fẹ́mi Akínṣọlá

Bí ọ̀rọ̀ ńlá kò bá tíì tán, èèyàn ńlá kò ní tíì sinmi àròyé.
Lásìkò tí ìgbẹ́jọ́ wọn ń lọ lọ́wọ́ èyí tí Ìgbìmọ̀ tó ń gbẹ́jọ́ nípa Àjọ NDDC ń ṣe, Sẹ́nétọ̀ Akpabio ní òun kò já ìlànà ìtọpinpin ìṣúná Àjọ náà gbà bẹ́ẹ̀ sì ni òun kò dá ẹnikẹ́ni dúró lẹ́nu iṣẹ́.

Àwọn nǹkan míì tí Sẹ́nétọ̀ Godswill Akpabio tún mẹ́nubà rèé pẹ̀lú bí ọ̀rọ̀ ṣe di fà kí n fà pẹ̀lú ìgbìmọ̀ tó ń gbẹ́jọ́ gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe n pò ó nínú pọ̀ pẹ̀lú ìbéèrè .

Sẹ́nétọ̀ Akpabio ní iṣẹ́ Mínísítà tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ẹkùn Niger Delta ni láti máa ṣe amójútó, kìí ṣe láti darí gbogbo nǹkan.

Akpabio ní òun kò ní èròńgbà kankan láti díje du ipò Ààrẹ Orílẹ̀ yìí. Bẹ́ẹ̀ òun kò ní kí òṣìṣẹ́ kankan kó bílíọ́nù mẹ́wàá náírà wá. Kò sí náírà kan tí ẹnikẹ́ni san fún un gẹ́gẹ́ bíi Mínísítà, òun kò sì gba kọngílá iṣẹ́ àkànṣe kankan fún Àjọ NDDC.

Ó tẹnu mọ́ ọ pé kò ṣeéṣe kí ogójì bílíọ́nù náírà sọnù lápò o NDDC torí pé àsùnwọ̀n owó kan ṣoṣo ni wọ́n ń lò. “Kò sí ẹni tó dá ná bílíọ́nù mẹ́jọ náírà. Gbogbo owó tí a ná ni bílíọ́nù mẹ́tàlélógún náírà kódà, kí Kofi-19 tó dé, ìdá ọgọ́ta àbá ètò ìṣúná Àjọ NDDC ló bá ètò ìlera lọ.

Akpabio ní láti ìgbà tí òun ti dé orí àlééfà, iṣẹ́ kọngílá mẹ́ta péré ni wọ́n gbà. Ó ní ibi tí Àjọ NDDC dé lónìí, torí àìsí amójútó tó péye ni.Ó tẹ̀síwájú pé kò sí ìwé fáìlì kankan tó sọnù torí àwọn ṣe ètò gbígbé ibi tí iṣẹ́ dé dúró lé àwọn tọ́rọ̀ kan lọ́wọ́ dáadáa.
Ó ní gbogbo rẹ̀ làwọn kó sílẹ̀ fún àyẹ̀wò ìwé ìṣúná Àjọ náà.

Akpabio fi kún-un pé, ìdá ọgọ́ta iṣẹ́ àkànṣe Àjọ NDDC ni ó jẹ́ pé àwọn ọmọ Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin ni wọ́n gbé e fún. Eléyìí gan ló wá di ọ̀rọ̀ rangbọndọn láàrin òun àtàwọn Aṣòfin báyìí.

Ẹ̀wẹ̀, ó ní òun yóó nílò ìfọwọ́sowọ́pọ̀ Ilé Aṣòfin láti fòpin sí pínpín iṣẹ́ àkànṣe NDDC mọ́ra wọn lọ́wọ́ nílé ìgbìmọ̀ Aṣòfin àti ṣíṣe àtúntò Àjọ náà.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Okorocha ketí ikún sí ìpé làwọn fi ṣígun kàá mọ́lé mọ́lé-EFCC

Wọ́n ní Okorocha ketí ikún sí ìpé làwọn fi ṣígun kàá mọ́lé mọ́lé Ọrẹ Òtítọ́jù Àjọ tó ń gbó…