Home ÀKỌ̀TUN Hèèmọ̀! Awakọ̀ tó pá Arotile kò níwèé àṣẹ ìwakọ̀
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - July 21, 2020

Hèèmọ̀! Awakọ̀ tó pá Arotile kò níwèé àṣẹ ìwakọ̀

Hèèmọ̀! Awakọ̀ tó pá Arotile kò níwèé àṣẹ ìwakọ̀

Fẹ́mi Akínṣọlá

Iléeṣẹ́ ológun òfurufú Nàìjíríà ti dárúkọ awakọ̀ tó fi ọkọ̀ pa awakọ̀-òfurufú jagun obìnrin àkọ́kọ́ ní Nàìjíríà, Tolulope Arotile.

Wọ́n ní awakọ̀ ọ̀hún, Nehemiah Adejoh kò ní ìwé àṣẹ láti wa ọkọ̀ lójú pópó.

Lọ́jọ́ tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé, Tolulope ń lọ sí ọjà Mammy nínú ọgbà iléeṣẹ́ náà tó wà ní Kàdúná ní Nǹkan bí aago mẹ́rin ààbọ̀ ìrọ̀lẹ́ kó tó pàdé àwọn akẹgbẹ́ẹrẹ̀ tẹ́lẹ̀ nílé iléeṣẹ́ ológun, Air Force Comprehensive School.

Àwọn akẹẹgbẹ́ rẹ̀ ọ̀hún, Nehemiah Adejoh, Igbekele Folorunsho àti Festus Gbayegun wa ọkọ̀ ayọkẹlẹ Kia Sorento tó ní nọńbà ìdánilójú AZ 478 MKA kọjá lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀.

Gẹ́gẹ́ bí ohun tí iléeṣẹ́ ológun òfurufú sọ, ìgbà tí Adejoh ń wa ọkọ̀ náà padà sẹ́yìn láti kí Tolulope ló kọlu u, èyí tó yọrí sí ikú rẹ̀.

Ìwádìí fi hàn pé Adejoh tí wọ́n fẹ̀sùn kàn pé ó ṣekúpa Tolulope kìí ṣe jagunjagun.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Adédoyin ṣépè fáwọn oníròyìn nílé ẹjọ́

Adédoyin ṣépè fáwọn oníròyìn nílé ẹjọ́ Ọrẹ Òtítọ́jù Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fáwọn oníròyìn láàárọ̀…