Home ÀKỌ̀TUN Akpabio sí aso̩ lójú eégùn fún ilé-ìgbìmo̩ asòfin
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - July 20, 2020

Akpabio sí aso̩ lójú eégùn fún ilé-ìgbìmo̩ asòfin

Akpabio sí aso̩ lójú eégùn fún ilé-ìgbìmo̩ asòfin

Yínka Àlàbí

Yoruba bo, won ni “ibere ija laa mo,ko seni to mo ipari re”. ” Oro kanle kan baale, yoo kan jeje ni mo jokoo mi”.
O ti to bi ojo meta ti iroyin sise owo to wa fun idagbasoke agbegbe Niger Delta ni maku-maku ti n lo.
Arabinrin to je adari agbegbe naa ti minisita Godwin Akpabio to n dari agbegbe naa yo lo koko bere si ni tu asiri Akpabio. O ni ko si bi minisita naa se le feran oun nitori awon o ki n koola nipa iwa ibaje.
O ni opo owo ni Akpabio maa n ni ki oun towo bo ti oun maa n yari mo o lowo. O ni nipa idi eyi, ko si bi o se le feran oun. Gbogbo ose to koja lo yii ni oro naa gbona janjan ti arabinrin naa n tu bi ejo. O di asiko kan ti won fe fi olopaa paa lenu mo ni aago merin oru ojo kan. Opelepo gomina Wike ti ipinle Rivers ni o gba obinrin naa sodo nigba ti awon to fe muu ko ni iwe ase lati odo oga olopaa kankan.
Eyi lo mun ki ile-igbimo asofin agba ranse pe alagba Godwin Akpabio ki o wa so ti enu re.
Akpabio ni oun ko ji owo kankan, o ni awon ile-igbimo asofin to ranse si oun gan-an ni eku eda to da wahala naa sile.
O ni gbogbo akanse ise to lowo lori ni awon ile-igbimo asofin n gba lati igba ti won ti da ajo naa sile.
Oro naa dabi igba ti eniyan yinbon si ilu nla. Kia ni won ni ki o dake, sugbon oun naa ko jale pe “ti e ba ni ki oro ma soko, eyi to wa lowo re yii, o maa so o”. Akpabio si aso loju eegun oro naa, o ni arabinrin Seneto to wa lorun oun le ma mo opo sugbon ki o bi awon oga re,o si je ki o yee pe, awon oga re ko le beere awon ibeere to o n jade lati enu re.
Eledua nikan lo le sedajo awon asofin rufin Naijiria.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo Ọrẹ …