Lọ́sẹ̀ tó ń bọ̀ ni awakọ̀-òfurufú jagun yóò wọ káà ilẹ̀ lọ l’Abuja
Lọ́sẹ̀ tó ń bọ̀ ni awakọ̀-òfurufú jagun yóò wọ káà ilẹ̀ lọ l’Abuja
Fẹ́mi Akínṣọlá
Iléeṣẹ́ ológun òfurufú ti kéde pé Ọjọ́bọ ọsẹ tó ń bọ̀ tíí ṣe ọjọ́ kẹtàlélógún oṣù keje ni awakọ̀-òfurufú jagun, Tolulope Arotile yóó wọ káà ilẹ̀ lọ.
Lọ́jọ́ Ẹtì ni iléeṣẹ́ ológun òfurufú kéde ọ̀rọ̀ náà lójú òpó abẹ́yefò Facebook rẹ̀.
Ọjọ́ kẹrìnlá oṣù keje ọdún 2020 yìí ni akọni awakọ̀-ofurufu jagun Tolu sàgbákò ikú òjijì nínú ìjàmbá ọkọ̀ nílùú Kàdúná.
Ayẹyẹ tí wọ́n máa ń ṣe fáwọn ológun ni wọn yóó ṣe fún olóògbé Tolulọpe ẹni ọdún mẹ́rìnlélógún.
Ní Mọ́súárì ileeṣẹ ológun tó wà nílùú Àbújá ni wọn yóó sin Tolu sí.
Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu
Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu Ọrẹ Òtítọ́jù Olùdíje fún i…