Home ÀKỌ̀TUN Ìwà àjẹbánu gbilẹ̀ lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà–Buhari
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - July 18, 2020

Ìwà àjẹbánu gbilẹ̀ lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà–Buhari

Ìwà àjẹbánu gbilẹ̀ lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà–Buhari

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ààrẹ Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Muhammadu Buhari ti ní lóòótọ́ ni ìwà ìbàjẹ́ àti jẹgúdújẹrá gbilẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Buhari sọ ọ̀rọ̀ yìí lásìkò tí ó ń fèsì fún ìgbà àkọ́kọ́ lórí bí wọ́n ṣe yọ Ibrahim Magu kúrò ní ipò gẹ́gẹ́ bí adarí Àjọ tó ń gbógun ti ìwà ìbàjẹ́ lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà, EFCC.

Ààrẹ ní gbogbo ọmọ Nàìjíríà gbọ́dọ̀ mọ̀ pé wọn yóó jíyìn ohun gbogbo tí wọ́n bá ṣe, papàá àwọn tó di ipò mu lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Ó ní bí ọwọ́ ṣìnkún àwọn agbófinró ṣe mú Magu fihàn pé kò sí ẹni tó kọjá òfin ní Nàìjíríà.

Ààrẹ Buhari lásìkò ìdìbò sípò Ààrẹ ní ọdún 2015 àti 2019 sọ wí pé ọ̀kan gbòógì nínú ohun tí ìṣèjọba òun yóó ṣe ni gbígbógun ti ìwà ìbàjẹ́.

Àmọ́, àwọn alátakò àti òǹwòye ọ̀rọ̀ ìlú ń sọ wí pé Ààrẹ Buhari kò ṣiṣẹ́ takuntakun nípa gbígbógun ti ìwà ìbàjẹ́, nítorí wọ́n fi ẹ̀sùn kan àwọn tó wà ní ìṣèjọba rẹ̀ fún ìwà ìbàjẹ́

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Adédoyin ṣépè fáwọn oníròyìn nílé ẹjọ́

Adédoyin ṣépè fáwọn oníròyìn nílé ẹjọ́ Ọrẹ Òtítọ́jù Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fáwọn oníròyìn láàárọ̀…