Home ÀKỌ̀TUN Ikú Tolu Arotile múfura dání – Afenifere, Gani Adams, Huriwa
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - July 17, 2020

Ikú Tolu Arotile múfura dání – Afenifere, Gani Adams, Huriwa

Ikú Tolu Arotile múfura dání – Afenifere, Gani Adams, Huriwa

Fẹ́mi Akínṣọlá

Yorùbá ní olè kò níí jàgbà kò má kó fìrí bẹ́ẹ̀ bí ọ̀rọ̀ bá rú ni lójú,à bi ilẹ̀ léèrè .

Èyí lo mú kí àwọn èèyàn kan máa pè fún ìwádìí lórí ikú tó pa obìnrin ológun àkọ́kọ́ tí yóó wa bàálù ní Nàìjíríà, Tolulope Arotile.

Àárọ̀ Ọjọ́rú ni ariwo ta pé ọkọ ọ̀rẹ́ Tolulope kan ló sàdédé kọ lu ọmọbìnrin náà, nígbà tó ń tara láti kí i.

Àmọ́ nígbà tí wọ́n ń tara lórí ikú ọmọbìnrin náà, Akọ̀wé fún ẹgbẹ́ Afẹ́nifẹ́re, Yinka Odumakin pẹ̀lú Ààrẹ ọ̀nà Kakanfo ilẹ̀ Yorùbá, Gani Adams àti ẹgbẹ́ òǹkọ̀wé totóẹ ajafẹtọ ẹni, Huriwa ní ọ̀rọ̀ ikú Tolulope náà mú ìfura lọ́wọ́.

Àtẹ̀jáde kan tí ẹgbẹ́ Afẹnifẹre fisita ni awọn alaye ti wọn n ṣe nipa iku to pa awakọ baalu ologun naa tako ara wọn, to si nilo ẹkunrẹrẹ iwadii.

“Kín ló dé tó jẹ́ pé ẹnìkan tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà sojú rẹ̀ ló tú àṣírí pé ọ̀rẹ́ rẹ̀ àtijọ́ kan ló fí ọkọ̀ kọlu ọmọbìnrin náà, àmọ́ tílé iṣẹ́ ológun òfurufú kàn kéde ikú rẹ̀ lásán, láì sàlàyé ọ̀nà tó gbà kú fún àráyé.”

Ààrẹ Gani Adams, nínú àtẹjáde kan tó fisíta láti bá mọ̀lẹ́bí Arotile kẹ́dùn, wá késí gbogbo àwùjọ àgbáyé láti tanná wádìí ohun tó ṣokùnfà ikú òjijì fún obìnrin náà nítorí ó mú ìfura lọ́wọ́.

” Báwo ni ọkọ̀ tó ń fi ẹ̀yìn rìn yóó kàn ṣe pa ọmọ ológo báyìí nínú ọgbà ológun? Ta ló wa ọkọ̀ ọ̀hún? Kín ni orúkọ rẹ̀, níbo sì ni onítọ̀ùn wà lọ́wọ́ lọ́wọ́?”

Ààrẹ Gani Adams ní ọ̀pọ̀ ìbéèrè ló ń rú jáde láti ipaṣẹ̀ ikú òjijì tó pa Arotile, tí kò tíì sí ìdáhùn fún rárá.

Ẹgbẹ́ òǹkọ̀wé ajàfẹ́tọ̀ ẹni HURIWA ń tiẹ̀ ń késí ilé Aṣòfin àpapọ̀ ilẹ̀ẹwa láti tọpinpin àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó rọ̀ mọ́ ikú Tolulope Arotile.

Huriwa ní bíìgbà tí wọ́n ń pa Ààlọ́ lásán ni wọ́n ṣe túfọ̀ ikú akọni obìnrin náà, èyí tí kò tẹ́ ọ̀pọ̀ ọmọ Nàìjíríà lọ́rùn.

Gbogbo àwọn èèyàn yìí wá bá mọ̀lẹ́bí Tolulope kẹ́dùn, tí wọ́n si gbàdúrà pé Ọba òkè yóó fún wọn ní ọkàn akin láti gba àdánù ńlá náà mọ́ra.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu

Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu Ọrẹ Òtítọ́jù Olùdíje fún i…