Home ÀKỌ̀TUN Alága àjọ EFCC t’ẹ́lẹ̀, Magu gba ìdásílẹ̀
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - July 16, 2020

Alága àjọ EFCC t’ẹ́lẹ̀, Magu gba ìdásílẹ̀

Alága àjọ EFCC t’ẹ́lẹ̀, Magu gba ìdásílẹ̀

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ọ̀rọ̀ fimọ lògbòlògbò yinmọ nù, ajá tó relé ẹkùn tó bọ̀ lọ̀rọ Adelé Alága àjọ EFCC, Ibrahim Magu dà bí Agbẹjọ́rò rẹ̀, Toyin Ojaomo ti fi tó iléeṣẹ́ Ìròyìn abẹ́lé kan létí pé Ọ̀gbẹ́ni Magu tí kúò nínú hàhámọ́.

Ibrahim Magu gba ìdàsílẹ̀ rẹ̀ lẹ́yìn tó lo ọjọ́ mẹ́wàá ní hàhámọ́. ìgbìmọ̀ olùwádìí tí Ààrẹ Orílẹ̀ yìí gbé kalẹ̀ láti wádìí ẹ̀sùn kòtọ́ àti ìwà màgòmágó tí agbẹjọ́rò àgbà l’órílẹ̀èdè Nàìjíríà, Amòfin Abubakar Malami fi kàn án.
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ti kọ́kọ́ ṣàlàyé pé àwọn kò mọ ohunkóhun nípa hàhámọ́ tí wọ́n fi Alága àjọ EFCC tí Ààrẹ Buhari yọ nípò sí.

Agbẹnusọ fún Ààrẹ Buhari, Fẹmi Adesina ṣàlàyé pé kò sí ẹni tó tíì fi ẹ̀sùn ọ̀daràn kan Magu, ìwádìí lásán ló ń wáyé lórí bí nǹkan ṣe ń lọ sí ní àjọ tó ń gbógun ti ìwà jẹgúdújẹrá lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà, EFCC.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Àwọn wọ̀nyí ti kékeré dèrò ẹ̀wọ̀n, jìbìtì orí ayélujára ló kó bá wọn

Àwọn wọ̀nyí ti kékeré dèrò ẹ̀wọ̀n, jìbìtì orí ayélujára ló kó bá wọn Ọrẹ Òtítọ́jù Àwọn ló …