Home ÀKỌ̀TUN Ikọ̀ Operation Burst” ní àwọn ló pa olórí àwọn “One million boys” n’Ìbàdàn
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - July 15, 2020

Ikọ̀ Operation Burst” ní àwọn ló pa olórí àwọn “One million boys” n’Ìbàdàn

Ikọ̀ Operation Burst” ní àwọn ló pa olórí àwọn “One million boys” n’Ìbàdàn

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ẹ̀dá yòówù tó bá ń tọrọ ọmọ lọwọ Elédùwà, ó sàn kì ò má fi ìwàǹwára bèèrè ò, kí ó má baà fi ìkánjú bí ìpọ́njú lọmọ. Ṣé àìlápò kò sàn ju àpò tó ń jò lọ.
Àì tètè r’ọ́mọ bi láyé sàn ju kí èèyàn dààmú bí ọ̀ràn bọnbọn bíi ìpátá, gbájúẹ̀ olè, jàgùdà páálí l’ọ́mọ.

Ọ̀gá àgbà ikọ̀ agbóguntìwà ọ̀daràn ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ èyí táa mọ̀ sí Operation Burst, Kọ́nẹ́ẹ̀lí Ọladipọ Ajibọla ti ṣàlàyé pé ikọ̀ náà ló ṣekúpa olórí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkuǹkùn One million boys ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Abíọ́lá Ẹbìlà lọ́jọ́ Àìkú.

Ọ̀gágun fẹ̀yìntì Ọladipọ Ajibọla ní ara ìgbésẹ̀ láti dẹ́kun ìwà ọ̀daràn àwọn ẹgbẹ́ ọ̀daràn àbi ẹgbẹ́ òkuǹkùn tó ń dá họ́wù họ́wù sílẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ní ó ṣokùnfà ikú Ẹbìlà.

Nígbà tó ń ṣàlàyé bí wọ́n ṣe pa aṣíwájú ẹgbẹ́ òkùnkùn náà, Kọ́nẹ́ẹ̀lì Ọladipọ ní, yàtọ̀ sí pé wọ́n yìnbọn pa Ẹbìlà lásìkò tó fi ń gbìyànjú láti sá mọ́ àwọn agbófinró lọ́wọ́ létí bèbè odò Kúdẹtì, àwọn ní ẹ̀rí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkuǹkùn one million boys tó wà pẹ̀lú rẹ̀ náà fi ara gbọta ìbọn.

Ó ní àwọn agbófinró ikọ̀ Operation Burst fẹ́ lọ dóòlà èèyàn kan táwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkuǹkùn náà kan jí gbé ni wọ́n fìjà pẹẹ́ta tí ìtàpórógan ìbọn sì wáyé l’éyì í tó ṣekú pa Ẹbìlà táwọn míràn sì tún fara gbọta.

Ó ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkuǹkùn náà kan gbé òkú Ẹbìlà lọ, síbẹ̀ àwọn leè sọ pé ọwọ́ dẹ níbi ìkọlù náà nítorí pé àwọn rí ẹni tí wọ́n jí gbé náà gbà padà, tí wọ́n sì tún sọsẹ́ sí ẹgbẹ́ òkuǹkùn náà.

” Àwọn alamí kan ló ta wá lólobó pé àwọn kan jí èèyàn kan gbé pamọ́ sínú àkọ́kù ilé kan lágbègbè Kúdẹtì.

Alamí náà ṣàlàyé fún wa pé mẹ́ta nínú àwọn ọmọlẹ́yìn Ẹbìlà jí èèyàn kan gbé, ni ikọ̀ operation Burst bá kó sẹ́nu iṣẹ́ lọ́gán nítorí àwa pẹ̀lú ti mọ̀ pé àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkuǹkùn One million boys ti sọ ara wọn ikọ̀ tí ń jalè lágbègbè náà.

Ní kété tí wọ́n rí wa, àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkuǹkùn tí wọ́n pera wọn ní mílíọ̀nù kan ọlọ́kùnrin” one million boys” bá bẹ̀rẹ̀ sí ní yìnbọn, níbi tí àwa náà ti ṣíná ìbọn bolẹ̀ fún wọn ni a ti pa Abíọ́lá Ẹbìlà, tí a sì wọ inú àkọ́kù Ilé náà lọ níbi tí a ti rí ẹni tí wọ́n jí gbé náà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Olufẹmi Awogboro tí a sì dóòlà ẹ̀mi rẹ̀.”

Ní tirẹ̀, Kọmíṣọ́nnà ọlọ́pàá ní Ìpínlẹ Ọ̀yọ́, Nwachukwu Enwonwu ṣàlàyé pé àwọn ọlọ́pàá kọ́ ló pa Ẹbìlà àti pé láti ọjọ́ Kọkànlá oṣù kẹrin ọdún yìí ni wọ́n ti ń wá Ẹbìlà lórí ikú Moshood Ọladokun tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Ẹ̀kúgbèmí tó jẹ́ olórí ẹgbẹ́ òkuǹkùn míràn nílùú Ìbàdàn.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ọwọ́ pálábá adigunjalè ẹlẹ́nimẹ́ta tó ja Tọpẹ Alabi lólè owó ṣégi

Ọwọ́ pálábá adigunjalè ẹlẹ́nimẹ́ta tó ja Tọpẹ Alabi lólè owó ṣégi Ọrẹ Òtítọ́jù Ọjọ́ gbogbo…