Home ÀKỌ̀TUN Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá Nàìjíríà ti kéde ètò ìgbani ṣíṣẹ́ lákọ̀tun
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - July 12, 2020

Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá Nàìjíríà ti kéde ètò ìgbani ṣíṣẹ́ lákọ̀tun

Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá Nàìjíríà ti kéde ètò ìgbani ṣíṣẹ́ lákọ̀tun

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ní báyìí, ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá Orílẹ̀ yìí ti fi léde pé àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tó bá ní àwọn amùyẹ wọ̀nyí nìkan ló lẹ́tọ̀ọ́ àti kópa nínú rẹ̀ ni
kí onítọ̀ùn wà láàrin ẹni ọdún mẹ́tàdínlógún sí mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n nìkan ló ní àǹfànì láti kópa nínú ètò náà.

Gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe sọ lójú òpó ìkànsíraẹni abẹ́yefò Twitter wọn.

Ìgbésẹ̀ fífi orúkọ sílẹ̀, fún tó bá setán àti kópa nínú ètò ìgbani ṣíṣe náà, ní láti kàn sí ojú òpó yìí www.policerecruitment.gov.ng/maintainance. tabi ki ẹ kan si http://policerecruitment.gov.ng/maintanance.html
kí olùkópa ó sì fi orúkọ rẹ̀ sílẹ̀ bí ó ti yẹ. Ẹ tẹ̀ẹ́ ní orí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ yín.

Kété tí ẹ bá ti dé ibí yìí ni kí ẹ pèsè àwọn ìfitónilétí bíi ibi tí ẹ ka ìwé dé, àwọn ìwé ẹ̀rí tí ẹ ní àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ báyìí:

Ṣaájú ni Bashir Ahmed tó jẹ́ olùbádàmọràn sí Ààrẹ Buhari lórí ìfitónilétí lórí ayélujára náà ti kọ́kọ́ fi sójú òpó abẹ́yefò twitter rẹ̀ nípa ètò ìgbani ṣíṣẹ́ náà

Díẹ̀ lára àwọn àmúyẹ kí wọ́n tó gba èèyàn ṣíṣẹ́ rèé:

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní ẹni tó bá fẹ́ kópa nínú ètò ìgbani ṣíṣẹ́ náà gbọdọ̀ ní èsì ìdánwò WAEC rẹ̀ pé nínú iṣẹ́ márùn ún, pẹ̀lú yíyege nínú èdè Òyìnbó (English language)

Bẹ́ẹ̀ ni kí ó dá pé lọ́mọkùnrin tàbí lọ́mọbìnrin láì ní àìsàn kankan lára.

Ó tún gbọdọ̀ jẹ́ ọlọ́pọlọ pípé tí kò ní àìsàn ọpọlọ.

Wọ́n ní aláboyún kò le kó pa lásìkò yìí àfi tó bá bímọ tán.

Onítọ̀ùn kò gbọdọ̀ kúrú ju ìwọn 1.67 fún ọkùnrin àti 1.64 fún obìnrin tó bá fẹ́ kópa.

Fífẹ̀ àyà rẹ gẹ́gẹ́ bíi ọkùnrin kò gbọdọ̀ pọ̀ ju ìwọn 34 inches lọ.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Okorocha ketí ikún sí ìpé làwọn fi ṣígun kàá mọ́lé mọ́lé-EFCC

Wọ́n ní Okorocha ketí ikún sí ìpé làwọn fi ṣígun kàá mọ́lé mọ́lé Ọrẹ Òtítọ́jù Àjọ tó ń gbó…