Home ÀKỌ̀TUN Àánú àwo̩n tí kò gbàgbó̩ pé covid-19 wà ń se mí – Sanwo-olu
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - July 11, 2020

Àánú àwo̩n tí kò gbàgbó̩ pé covid-19 wà ń se mí – Sanwo-olu

Àánú àwo̩n tí kò gbàgbó̩ pé covid-19 wà ń se mí – Sanwo-olu

Yínkà Àlàbí

Gomina ipinle Eko,Alagba Babajide Sanwo-olu lo n salaye yii fun awon alase ati awon akekoo ile-iwe Corona ni ilu Eko.
O ni o se oun laanu pe bi ijoba ibile,ipinle ati ijoba apapo se n pariwo to lori redio, telifison ati awon iwe iroyin gbogbo. Awon kan si tun ko agidi bole pe ko si oun to n je covid-19.
Gomina ni ti won ko ba tile fe gba ti ile yii gbo, se bi won n gbo tabi ri ti awon orileede agbaye to ku.
O ni awon kan tile ro pe arun olowo ni,gomina salaye pe ko si eni ti ko le mu.
Gomina ni eyi to je ki o maa daru mo awon kan loju ni iroyin awon to loruko ti ajakale arun naa n ba ja ati awon to n pa ti won n gbo. O ni aimoye eni ti ko loruko ni arun naa ti ko lu bee si ni aimoye lo ti ran lo si orun osan gan-an.
Sanwo-olu ni opo ni ko tile de ile iwosan rara ti o je wi pe covid-19 naa lo pa won.
Gomina tun ro awon akekoo pe ki won ni suuru pelu ijoba nitori alafia won lo je ijoba logun. O ni o di igba ti arun yii ba ko ara re kuro nile ki won to le wole eko won. O si gba won niyanju ki won ma se so ireti nu nipa yiye iwe won wo nigba gbogbo. Ori ero ayelujara zoom ni ipade naa ti waye.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Okorocha ketí ikún sí ìpé làwọn fi ṣígun kàá mọ́lé mọ́lé-EFCC

Wọ́n ní Okorocha ketí ikún sí ìpé làwọn fi ṣígun kàá mọ́lé mọ́lé Ọrẹ Òtítọ́jù Àjọ tó ń gbó…