Home ÀKỌ̀TUN Ó dìgbà! Aṣòfin Tunde Braimoh wọlẹ̀ káà ilẹ sùn l’Ékò
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - July 10, 2020

Ó dìgbà! Aṣòfin Tunde Braimoh wọlẹ̀ káà ilẹ sùn l’Ékò

Ó dìgbà! Aṣòfin Tunde Braimoh wọlẹ̀ káà ilẹ sùn l’Ékò

Fẹ́mi Akínṣọla

Awaye ku ko sin, ọrun ma kanju, gbogbo wa la n bọ.

Irọlẹ ọjọ ni wọn fi ilẹ bo oku asofin Tunde Braimoh ni asiri nilu Eko ni deedee aago meji ọsan.

Itẹ́ òkú Vault Garden, tó wà ní Awoyaya lẹ́bàá Mayfair Garden ní àdúgbò Lekki nílù Eko ni wọn sin asofin Braimoh si.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ẹbí, ọ̀rẹ́, ojúlùmọ̀ àti alájọse nídìí òsèlú ló ti péjú sílé rẹ̀ láti dárò ikú rẹ̀, àmọ́ ẹ̀tahóró wọn ló báwọn péjú síbi tí wọ́n ti sin òkú rẹ̀.

Èyí kò sì ṣẹ̀yìn òfin títa kété síra ẹni tó wà n’íta, àwọn tó sì péjú sin aṣòfin náà kò pé mẹ́wàá níye.

Àwọn abánikẹ́dùn ti yabo ilé Tunde Braimoh, aṣòfin ìpínlẹ̀ Èkó tó jáde láyé ní òwúrọ̀ ọjọ́ Ẹtì.

Àwọn olólùfẹ́ olóògbé náà tó ń sọ̀rọ̀ tẹ̀dùn-tẹ̀dùn pé aláànú kan ṣoṣo tó kù fún àwọn ni wọ́n fi dá wọn lóró.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò le fìdí irú ikú tó pa olóògbé ọ̀hún múlẹ̀, àmọ́ ó ta sí akọròyìn l’étí pé, ibùdó ìtọ́jú alárùn Kòrónáfairọ̀ọ̀sì tó wà ní àdúgbò Yaba, ni Braimoh kú sí.

Kò tí ì pé oṣù kan tí aṣòfin tó ń ṣojú ẹkùn ìdìbò Kosofe, nílé aṣòfin àgbà Nàìjíríà, Bayo Osinowo jáde láyé.

Aṣòfin Braimoh ló ń ṣojú ẹkùn ìdìbò Kosofe kejì nílé aṣòfin ìpínlẹ̀ Èkó.

Bákan náà ni aṣòfin Buraimoh ti se Alága Ìjọba ìbílẹ̀ Kosofe rí, tó sì tún jẹ́ aṣojú sòfin fágbègbè Kétu.

Ní nǹkan bí oṣù méjì sí àsìkò yìí, ni Braimoh kò bá pé ẹni ọgọ́ta ọdún lókè èèpẹ̀.

Kódà nínú àwọn tó ṣètò ìsìnkú, tó sì gbàlejò Gómìnà Èkó, Babajide Sanwoolu nílé aṣòfin àgbà, Adebayo Osinowo tá a mọ̀ sí Pepperito, lásìkò tó jáde láyé ni Braimoh wà.

Èyí ló mú kí àwọn kan má a sọ pé, ó ṣeéṣe kí ó ti kó àrùn Kofi-19 ṣùgbọ́n a kò tí lè fìdí ọ̀rọ̀ yí múlẹ̀.

Gẹ́gẹ́ bí mọ̀lẹ́bí rẹ̀ kan tó fi ìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ ti wí, ìdájí àárọ̀ ọjọ́ Ẹtì òní ni aṣòfin náà jawà á lẹ̀. , kò sì tíì sí ẹni tó leè fìdí ohun tó ṣokùnfà ikú rẹ̀ múlẹ̀.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ilé ẹjọ́ tú el-zakzaky àti ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀

Ilé ẹjọ́ tú el-zakzaky àti ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀ Fẹ́mi Akínṣọlá Ajá tó relé ẹkùn tó bọ̀,ó tọ́ kí…