Home ÀKỌ̀TUN Hushpuppi di ẹlẹ́wọ̀n tó ní nọ́ńbà l‘Amẹrika
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - July 10, 2020

Hushpuppi di ẹlẹ́wọ̀n tó ní nọ́ńbà l‘Amẹrika

Hushpuppi di ẹlẹ́wọ̀n tó ní nọ́ńbà l‘Amẹrika

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé ọjọ́ gbogbo ni ti olè, ọjọ́ kan ṣoṣo ni ti olóhun. lkún Ramoni Olorunwa Abbas tí ìnagijẹ rẹ̀ ń jẹ́ Hushpuppi ń jọ̀gẹ̀dẹ̀, ó ń rẹ́dìí, ikún rẹ̀ kò mọ̀ pé ń tó dùn ń pani.
Èyí ló bí Ìròyìn tuntun tí Iléeṣẹ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n l’órílẹ̀èdè Amẹ́ríkà, fi síta nípa ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Hushpuppi pé, ó ti wà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n nílù Chicago, Illinois.

Ọwọ́ ọlọ́pàá ìlú Dubai tẹ Ramoni Olorunwa Abbas, tí ìnagijẹ rẹ̀ ń jẹ́ Hushpuppi, láìpẹ́ yìí, fún ẹ̀sùn lílu jìbìtì lórí ayélujára.

Lẹ́yìn náà ni wọ́n fi ránṣẹ́ sí orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.

Alẹ́ ọjọ́ Ajé sì ni iléeṣẹ́ Ọgbà ẹ̀wọ̀n fi orúkọ Hushpuppi sí orí ìtàkùn àgbáyé wọn.

Kódà, wọ́n ti fún Hushpuppi ní nọ́ńbà ìdánimọ̀ l’ọ́ọgbà ẹ̀wọ̀n, 54313-424, èyí tí yóó fún àwọn èèyàn l’áǹfàní láti kà nípa rẹ̀ lórí itàkùn àgbáyé náà.

Àwọn nǹkan míràn nípa rẹ̀ tó tún wà níbẹ̀ ni, orúkọ, ọjọ́ orí, àti ẹ̀yà rẹ̀.

Ọ̀sẹ̀ bí i mélò kan sì ni iléeṣẹ́ ètò Ìdájọ́ ilẹ̀ Amẹ́ríkà yóó gbé ẹni ọdún mẹ́tàdínlógójì ọ̀hún lọ sí ìlú Los Angeles, láti jẹ́jọ́ lórí ẹ̀sùn lílu jìbìtì.

Bí ọwọ́ ọlọ́pàá ṣe tẹ Hushpuppi, àti Lekan Ponle AKA Woodberry, tí wọ́n sì gbé wọn lọ sí orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, fa àríyànjiyàn lórí ayélujára.

Èèyàn mẹ́wàá míràn ni àwọn ọlọ́pàá ìlú Dubai, kò pọ̀ mọ́ Hushpuppi àti Woodberry, nínú àkànṣe iṣẹ́ kan tí wọ́n pè ní ‘Fox Hunt 2’.

Ẹ̀sùn lílu jìbìtì, kíkó owó pamọ́ lọ́nà àìtọ́, jíja báńkì lólè, fífi ara ẹni pé ẹlòmíì , ni wọ́n fi kan wọ́n.

Lásìkò tí àwọn ọlọ́pàá mú Hushpuppi, ọwọ́ wọ́n tẹ àwọn ìwé àkọsílẹ̀ nípa jìbìtì kan, tí owó rẹ̀ tó òjìlé nírinwó dín márùn ún mílíọ̀nù Dọ́là, t’óun ń múrasílẹ̀ fún.

Bákan náà ni wọ́n tún gba àwọn nǹkan yìí lọ́wọ́ rẹ̀:
Owó tó lé ní $40.9 mílíọ̀nù
Ọkọ̀ ayọ́ kẹ́lẹ́ bọ̀gìnnì mẹ́tàlá
Ẹ̀rọ ayára bí àṣà mọ́kànlélógún
Ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ alágbèéká mẹ́tàdínláàdọ́ta, àti àwọn nǹkan míràn
Iye èèyàn tí wọ́n ló ti lù ní jìbìtì kù díẹ̀ kó pé mílíọ̀nù méjì (1,926,400).

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ọwọ́ pálábá adigunjalè ẹlẹ́nimẹ́ta tó ja Tọpẹ Alabi lólè owó ṣégi

Ọwọ́ pálábá adigunjalè ẹlẹ́nimẹ́ta tó ja Tọpẹ Alabi lólè owó ṣégi Ọrẹ Òtítọ́jù Ọjọ́ gbogbo…