Home ÀKỌ̀TUN Ẹ kú àṣẹ̀yìndè, Tinubu yọjú sí aya Ajímọ̀bi
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - July 10, 2020

Ẹ kú àṣẹ̀yìndè, Tinubu yọjú sí aya Ajímọ̀bi

Ẹ kú àṣẹ̀yìndè, Tinubu yọjú sí aya Ajímọ̀bi

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé wọ́n ní bẹ́ni bá kú, ẹni náà ní-ín ku ni-ín kù.
Aṣíwájú Bola Tinubu náà ti lọ kí Florence Ajímọ̀bi kú àṣẹ̀yìndè Abíọ́lá Ajímọ̀bi o.
Àgbà ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress (APC), Aṣíwájú Bola Ahmed Tinubu ti lọ kí àyà oloogbe Abiola Ajimobi to jẹ gomina ipinlẹ Oyo tẹlẹ, pé, ó kú ará fẹ́ra kú baálé rẹ̀ tí kò sí mọ́.

Lónìí, ọjọ́ Ẹtì ni Bola Tinubu kan sílé olóògbé ní Ìbàdàn láti kí aya olóògbé, Florence Ajímọ̀bi.

Lára àwọn tó kọ́wọ̀ọ́ rìn pẹ̀lú Ahmed Tinubu ni Oba Elegushi ti ilẹ Ikate, Oba Saheed Ademola Elegushi.

Kábíèsí náà wá kí aya Sẹ́nétọ̀ Abíọ́lá Ajímọ̀bi kú ara fẹ́ ara kù pẹ̀lú àdúrà pé kí Ọlọ́run dẹ ilẹ̀ fún ẹni tó lọ.

Ọpọ èèyàn ló gbà pé ọmọ rere lẹ́yìn Aṣíwájú Bola Ahmed Tinubu ni gómìnà àná ní ìpínlẹ̀ Oyo tí wọ́n ṣe ọjọ́ kẹjọ àdúrà òkú rẹ̀ lọ́sẹ̀ tó kọjá.

Kí ọlọ́jọ́ tó dé, Abíọ́lá Ajímọ̀bi ni ìgbákejì Alága ẹgbẹ́ òṣèlú APC ní ẹkùn Gúúsù Nàìjíríà àti adelé Alága ẹgbẹ́ òṣèlú APC lápapọ̀.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run Ọrẹ Òtítọ́jù Ayẹyẹ ọjọ́ọ̀bì à…