Home ÀKỌ̀TUN Ẹ má fepo àjẹbánu yímí lásọ lórí ọ̀rọ̀ Magu–Oṣinbajo
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - July 9, 2020

Ẹ má fepo àjẹbánu yímí lásọ lórí ọ̀rọ̀ Magu–Oṣinbajo

Ẹ má fepo àjẹbánu yímí lásọ lórí ọ̀rọ̀ Magu–Oṣinbajo

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé wọ́n ní bí ará ilé è rẹ́ bá lẹ́nu, ìwọ náà ríi pé o lẹ́sẹ̀. Èyí ló mú kí Ìgbákejì Ààrẹ Orílẹ̀ yìí Yemi Osinbajo ó sẹ́ kanlẹ̀, lórí àhesọ ìròyìn kan tó ní Ibrahim Magu, Alága Àjọ EFCC tẹ́lẹ̀rí, ti jẹ́wọ́ pé, òun tẹ́wọ́ gba mílíọ̀nù mẹ́rin Náírà lọ́wọ́ rẹ̀.

Àtẹjáde kan tí akọ̀wé ìròyìn sí ìgbákejì Ààrẹ, Laolu Akande fisíta ní irọ tó jìnà sóòótọ́ ni àwọn ìròyìn isẹlẹ náà, tó wà láwọn ojú òpó ìròyìn kan.

Àwọn ìwé ìròyìn kan ló gbé ìròyìn náà jáde pé, wọ́n fi ẹ̀sùn kan Ibrahim Magu pé, ó kó owó tó tó bílíọ́nù mọ́kàndínlógójì náírà jọ, tó sì fún Osinbajo ní bílíọ́nù mẹ́rin náírà nínú rẹ̀.

Ẹ̀sùn míràn tí wọ́n tún fi kan ìgbákejì Ààrẹ nínú àwọn ìròyìn náà ni pé, ó pàṣẹ fún àjọ EFCC láti wọ́gilé àwọn ìpinnu rẹ̀ kan láì tẹ̀lé òfin tó yẹ.

Àmọ́ ìgbákejì Ààrẹ ti ní òfúùtù fẹ́ẹ̀tẹ̀, áásà tí kò ní kán-ún ni àwọn ẹ̀sùn náà, tó sì sàpèjúwe wọn bíi ara ọna lati ta epo si aṣọ ààlà òun lójú aráyé ni.

Laolu Akande wá sàlàyé pé, ìgbákejì Ààrẹ ní òun kò ní fààyè gba irúfẹ́ àwọn ìròyìn èké yìí láti si i òun lọ́nà nídìí ṣíṣe iṣẹ́ ìlú bó se yẹ.

Àtẹ̀jáde kan tó fi síta ni Ọṣinbajo ti kéde pé òun ti fa ọ̀rọ̀ yìí lé àwọn agbófinró lọ́wọ́ fún ìwádìí àti ìgbẹ́jọ́ tó yẹ.

Bẹ́ẹ̀ bá gbàgbé, Ibrahim Magu tíí ṣe adelé Alága fún àjọ EFCC fún ọdún Márùn-ú, ni ìgbìmọ̀ kan tí Ààrẹ gbé kalẹ̀ ń tanná wádìí rẹ̀ lọ́wọ́, lórí ẹ̀sùn ìwà àjẹbánu àti àìgbọnràn sí àwọn aláṣẹ.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu

Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu Ọrẹ Òtítọ́jù Olùdíje fún i…