Home ÀKỌ̀TUN Aminu Adisa Logun d’olóògbé pẹ̀lú àrùn Kofi-19
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - July 8, 2020

Aminu Adisa Logun d’olóògbé pẹ̀lú àrùn Kofi-19

Aminu Adisa Logun d’olóògbé pẹ̀lú àrùn Kofi-19

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwáyé è kú kan kò sí, ìgbà, àsìkò àti ọ̀nà tí kóówá ó gbà padà lọ́dọ̀ Adẹ́dàá lò sọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, èyí náà ló díá fún ìkéde pàjáwìrì tó tẹ akọròyìn lọ́wọ́ pé Olórí òṣìṣẹ́ Ìjọba ìpínlẹ̀ Kwara, Aminu Adisa Logun ti dágbére fáyé lẹ́ni ọdún mẹ́taleláàdọrin lẹ́yìn tó lùgbàdì àrùn Kofi-19.

Akọ̀wé Ìjọba ìpínlẹ̀ náà, Rafiu Ajakaye ló fi ọ̀rọ̀ náà léde fún akọròyìn.

Àtẹ̀jáde náà ní “Logun jẹ́ ìpè Elédùwà lálẹ́ ọjọ́ Ìṣẹ́gun lẹ́yìn wákàtí díẹ̀ tí èsì àyẹ̀wò fi hàn pé ó ti ní àrùn Kofi-19.”

Ó tẹ̀síwájú pé Ìjọba àtàwọn èèyàn ìpínlẹ̀ Kwara ti pàdánù ẹni iyì tó sin Ìjọba ìpínlẹ̀ ọ̀hún pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ̀ kí ọlọ́jọ́ tó dé.

Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ti mú kí Gómìnà ìpínlẹ̀ náà, AbdulRahman AbdulRazaq kéde ọ̀fọ̀ ọjọ́ méje láti fi ṣèdárò olóògbé ọ̀hún.

Lẹ́yìn náà ló ní Gómìnà ọ̀hún bá ẹbí olórí òṣìṣẹ́ Ìjọba tẹ́lẹ̀rí náà àti gbogbo àwọn olùgbé ìlú Ilorin kẹ́dùn ikú rẹ̀.

Akọ̀wé Ìjọba parí àtẹ̀jáde náà pé àwọn ẹbí olóògbé náà àti Ìjọba yóó kéde bí ètò ìsìnkú rẹ̀ yóó ṣe lọ láìpẹ́.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Okorocha ketí ikún sí ìpé làwọn fi ṣígun kàá mọ́lé mọ́lé-EFCC

Wọ́n ní Okorocha ketí ikún sí ìpé làwọn fi ṣígun kàá mọ́lé mọ́lé Ọrẹ Òtítọ́jù Àjọ tó ń gbó…