Home ÀKỌ̀TUN Akérédolú jàjàbọ́ lọ́wọ́ àrùn Kofi-19
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - July 7, 2020

Akérédolú jàjàbọ́ lọ́wọ́ àrùn Kofi-19

Akérédolú jàjàbọ́ lọ́wọ́ àrùn Kofi-19

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ọ̀ràn fimọ lògbòlògbò yinmọ nù,ni àrùn apinni léèmí, ajániláyà pàtì , Kòrónáfairọ̀ọ̀sì fi Gómìnà Ìpínlẹ̀ Òǹdó ṣe o, bí Gómìnà náà, Rótìmí Akérédolú ti rí àánú gbà, jàjàbọ́ lọ́wọ́ àrùn ọ̀hún.

Akérédolú ló fi ọ̀rọ̀ náà léde nígbà tó ń jábọ̀ ibi iṣẹ́ dé dúró lórí bí ìpínlẹ̀ náà ṣe ń gbógun ti àjàkálẹ̀ àrùn ọ̀hún lọ́jọ́ Ajé.

Ó ní “Gẹ́gẹ́ bí gbogbo yín ṣe mọ̀, èmi náà jẹ́ ọ̀kan lára àwọn èèyàn tó ní àrùn Kofi-19, tí mi ò sì ṣàfihàn àpẹrẹ àrùn náà.”

“Lẹ́yìn tí mo lo ọjọ́ díẹ̀ ní ìdánìkànwà ni mo ṣe àyẹ̀wò míràn gẹ́gẹ́ bí àgbékalẹ̀ àjọ NCDC, ìṣẹ́jú díẹ̀ sẹ́yìn ni mo gba èsì àyẹ̀wò náà, tó sì fi hàn pé mi ò ní àrùn ọ̀hún mọ́.”

Akérédolú sọ pé ọjọ́ díẹ̀ tí òun lò ní ìgbélé fún òun láyè láti ro àròjinlẹ̀ lórí àwọn ìpèníjà tí Kofi-19 mú bá ìpínlẹ̀ Òǹdó.

Lọ́wọ́ yìí, irinwó lé mẹ́rìndinlọ́gọ́ta èèyàn ló ti ní àrùn náà ní ìpínlẹ̀ Òǹdó.

Ọgbọ̀n ọjọ́ oṣù Kẹfà ọdún 2020 ni Gómìnà ọ̀hún kéde pé òun ti lùgbàdi àrùn náà, lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀ si ni Kọmíṣọ́nnà ètò ìlera ìpínlẹ̀ ọ̀hún, Wahab Adegbenro dágbére fáyé.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo Ọrẹ …