Home ÀKỌ̀TUN Wọ́n dá ikọ̀ ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ padà níbi fìdáù Ajímọ̀bi
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - July 6, 2020

Wọ́n dá ikọ̀ ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ padà níbi fìdáù Ajímọ̀bi

Wọ́n dá ikọ̀ ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ padà níbi fìdáù Ajímọ̀bi

Fẹ́mi Akínṣọlá

Egbìnrìn ọ̀tẹ̀, wọ́n ń gbìyànjú àti pàkan, òmí-ìn ń rú tú ú ni ọ̀rọ̀ náà jọ ọ, bí ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti sọ pé òun kò mọ ìdí tí wọ́n ṣe dá ikọ̀ asojú òun padà lẹ́nu ọ̀nà ilé Gómìnà àná, Abíọ́lá Ajímọ̀bi, nígbà tó yọjú síbi àdúrà ọjọ́ kẹjọ lẹ́yìn tó papòdà.

Olùrànlọ́wọ́ pàtàkì fún ìgbákejì Gómìnà lórí ọ̀rọ̀ tó ń lọ, Omoetan Omolere ló sọ bẹ́ẹ̀ fún akọròyìn.

Omolere ní àwọn ẹ̀ṣọ́ ilé Gómìnà àná ọ̀hún sọ fún àwọn ẹ̀ṣọ́ ìgbákejì Gómìnà pé, ọwọ́ ìyàwó olóògbé náà ni kọ́kọ́rọ́ ẹnu ọ̀nà wà, àti pé kí ìgbákejì Gómìnà má ṣèyọnu láti jáde kúrò nínú ọkọ̀ tó gbé e wá.

Ó ní “Lára àwọn ẹ̀ṣọ́ tó wà lẹ́nu ọ̀nà ló sọ fún àwọn èèyàn wa pé, ká má tilẹ̀ jáde kúrò nínú ọkọ̀ wa nítorí wọn kò ní sílẹ̀kùn fún wa.”

Ní ti pé bóyá èdè àìyedè ti wà láàrin ìyàwó Ajímọ̀bi àti ìgbákejì Gómìnà tẹ́lẹ̀rí, Omoetan ní òun kò lè sọ bóyá ìjà wà láàrin àwọn méjéèjì saájú ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

Gẹ́gẹ́ bó ṣe sọ, ó ní kìí ṣe ìgbákejì Gómìnà nìkan ni wọ́n lé padà lẹ́nu ọ̀nà ilé olóògbé náà.

Ó ní wọ́n tún lé àwọn Kọmíṣọ́nnà méjì míràn, àti ìyàwó Gómìnà tẹ́lẹ̀rí ní ìpínlẹ̀ ọ̀hún, Alhaja Mutiat Ladoja, tó jẹ́ ìyàwó Sẹ́nétọ̀ Rasheed Ladoja padà lẹ́nu ọ̀nà.

Omolere parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé “Kìí ṣe Rauf Olaniyan ni wọ́n dá padà lẹ́nu ọ̀nà Gómìnà Abíọ́lá Ajímọ̀bi, bí kò ṣe Ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.”

“Nítorí kò lọ síbi àdúrà náà lórúkọ ara rẹ̀, ṣùgbọ́n ó lọ lórúkọ ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.”

Ẹ̀wẹ̀, agbẹnusọ fún Abíọ́lá Ajímọ̀bi, Bolaji Tunji ti sọ nínú àtẹjáde kan pé kìí ṣe pé àwọn mọ̀ọ́mọ̀ le ìgbákejì Gómìnà padà níbi àdúrà ọjọ́ kẹjọ ọ̀hún, ṣùgbọ́n ó wá lásìkò tí kò yẹ ni.

Tunji sọ pé ìgbákejì Gómìnà náà dé lẹ́yìn tí àdúrà ti bẹ̀rẹ̀ àti pé, àwọn ẹbí olóògbé nìkan ni àdúrà ọ̀hún wà fún.

Ó tẹ̀síwájú pé, wọ́n gbé kọ́kọ́rọ́ ṣẹ́nu ọ̀nà ní títẹ̀lé ìlànà ìjìnàsíraẹni gẹ́gẹ́ bí àjọ NCDC ṣe gbé e kalẹ̀, lọ́nà àti dẹ́kun ìtànkálẹ̀ àrùn Kofi-19.

Tunji sọ pé yàtọ̀ sí pé kò sí ẹnikẹ́ni tó mọ̀ pé ìgbákejì Gómìnà yóó yọjú síbi àdúrà náà, wọ́n gbìyànjú láti pé ìgbákejì Gómìnà náà padà, ṣùgbọ́n ó ti kúrò níbi tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run Ọrẹ Òtítọ́jù Ayẹyẹ ọjọ́ọ̀bì à…