Home ÀKỌ̀TUN Kọmíṣọ́nnà ètò ìlera ìpínlẹ̀ Ondo wọlẹ̀ sùn
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - July 3, 2020

Kọmíṣọ́nnà ètò ìlera ìpínlẹ̀ Ondo wọlẹ̀ sùn

Kọmíṣọ́nnà ètò ìlera ìpínlẹ̀ Ondo wọlẹ̀ sùn

Fẹ́mi Akínṣọlá

Kọmíṣọ́nnà fún ètò ìlera ní ìpínlẹ̀ Òǹdó, Wahab Adegbenro ti wọlẹ̀ sùn ní Ọjọ́ Ẹtì.

Adegbenrọ ni wọ́n sin sí ilé rẹ̀ tó wà ní Ìlárá Mọkin ní Ìjọba ìbílẹ̀ Ìfẹ́ dọ̀rẹ́ ní déédé aago mẹ́wàá Òwúrọ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀sìn Mùsùlùmí ṣe làá kalẹ̀.

Adegbenro, tíí se ọmọ bíbí ìlú Ìlárá Mọkin nípìńlẹ̀ Òǹdó, ni wọ́n kéde ikú rẹ̀ lẹ́yìn ọjọ́ méjì tí Gómìnà ìpínlẹ̀ náà, Rotimi Akérédolú kéde pé òun náà ti lùgbàdi àrùn Kofi-19.

Mọ̀lẹ́bí olóògbé náà, Rasheed sàlàyé pé Kọmísánà náà se ìṣẹ́ abẹ fún aláìsàn kan lọ́jọ́ Ajé nílé ìwòsàn àdáni rẹ̀ tó wà ní Odo Ikoyi.

Àmọ́ sàdédé ló ṣubú lulẹ̀, tó sì dákú lọ rangbọndan, kí wọ́n tó gbé e dìgbà-dìgbà re ilé ìwòsàn.

Gẹ́gẹ́ bá a se gbọ́ ibùdó tí wọ́n ti ń tọ́jú àwọn alárùn kòrónáfairọ̀ọ̀sì nílùú Àkúrẹ́ ni Kọmíṣọ́nnà náà dákẹ́ sí.

Ẹbí, ará àti ọ̀rẹ́ pẹ̀lú ojúlùmọ̀ ló péjú p’ésẹ̀ sí ibi ìsìnkú náà.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Okorocha ketí ikún sí ìpé làwọn fi ṣígun kàá mọ́lé mọ́lé-EFCC

Wọ́n ní Okorocha ketí ikún sí ìpé làwọn fi ṣígun kàá mọ́lé mọ́lé Ọrẹ Òtítọ́jù Àjọ tó ń gbó…