Home ÀKỌ̀TUN Àjọ PPPRA ti fowó kún jálá epo bẹtiróò
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - July 1, 2020

Àjọ PPPRA ti fowó kún jálá epo bẹtiróò

Àjọ PPPRA ti fowó kún jálá epo bẹtiróò

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ìjọba ti kéde ẹ̀kúnwó epo bẹntírò láti ọgọ́rùn ún náírà lé ní náírà mọ́kànlélógún àbọ̀ (N121.50) sí náírà mẹ́tàlélógóje lé ní ọgọ́rin kọ́bọ̀(N 143.80).

Àjọ PPPRA tó ń ṣàmójútó owó epo rọ̀bì ló ṣe ìkéde náà nínú àtẹ̀jáde kan tó fi síta lọ́sàn Ọjọ́rú.

Àjọ náà ni “lẹ́yìn àgbéyẹ̀wò kíkún àti nǹkan ti ọjà epo bẹtiróò ń sọ lágbàyé nínú oṣù kẹfà, àwọn ṣe àmójútó ìyé tó to gbé epo jáde tí ẹnikẹ́ni kò sì ní pàdánù owó”

“Nítorí náà, a rọ àwọn ilé epo láti máa ta jálá epò bẹtiróò ní ogóje náìrà sí náírà mẹ́tàlélógóje ó lé ọgọ́rin kọ́bọ̀, fún oṣù keje ọdún 2020.”

A rọ gbogbo àwọn ilé epo aládàáni kí wọ́n ta ọjà wọ́n ni gbèdéke iye tí PPPRA pè é.

Ẹgbẹ́ àwọn aládàáni tó ń ta epo bẹtiró ní Nàìjíríà (IPMAN) ti sàlàyé pé, gbogbo ìlànà tí ìjọba là sílẹ̀ ni àwọ́n ń tẹ̀lé nípa títa epo bẹtiró.

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, Ààrẹ ẹgbẹ́ IPMAN ní Nàìjíríà Chinedu Okoronkwo sàlàyé pé, ẹ̀dínwó epo látọ̀dọ̀ ìjọba tí kásẹ̀ nílẹ̀, síbẹ̀ àjọ tó ń rí sí iye owó tí wọ́n ń ta epo lábẹ́lé náà ń fi gbèdéke iye tí ilé epo aládàáni gbọdọ̀ ta epo síta.

Ó ní gbogbo ọmọ ẹgbẹ́ ló ń tẹ̀lé àṣẹ́ Ìjọba nípa títà á ni ìye ti ijọba sọ, tí àwọn míràn tilẹ̀ ń tà á ní iye tó tún kéré jù bẹ́ẹ̀ lọ.

Okoronkwo ní ọ̀pọ̀ ló ń fi náírà méjì, mẹ́ta tà á nítorí wọ́n fẹ́ padà lọ ra òmíràn lásìkò, kí wọ́n sì pa owó wọ́n kí wọ́n sì kó èrè wọ́n jọ.

Nígbà ti akọròyìn bèèrè lórí ìdí tí àwọn alágbàtà míràn fí ń ta jálá epo kan ní náírà márùndínláàdóje, nígbà tí ìjọba ní kí wọ́n máa tà á ní náírà mọ́kànlélọ́gọ́fà àbọ̀, Okonkwo sọ pé àsìkò péréte náà ló kù tí irú wọn kò fì ní lè ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́ nítorí tí ará ìlú bá rí ibi tí epo ti dínwó, wọn kò ní lọ sí ibi tí ó ti wọ́n.

Náírà mọ́kàndínlọ́gọ́fà ní àwọn ilé epo míràn ń tà á ní ìpínlẹ̀ Porthacourt, sùgbọ́n láìpẹ́ nǹkan tí olúkúlùkù bá rà, ni wọn ó tà, ẹni tó bá sì ra ọjà ọ̀wọ́n, náà ni yóò wá bí yóò ṣe tà á.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo Ọrẹ …