Home ÀKỌ̀TUN K’áwọn olùkọ́ wọlé, a ó sètò pípe akẹ́kọ̀ọ́ — Mákindé
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - June 24, 2020

K’áwọn olùkọ́ wọlé, a ó sètò pípe akẹ́kọ̀ọ́ — Mákindé

K’áwọn olùkọ́ wọlé, a ó sètò pípe akẹ́kọ̀ọ́ — Mákindé

Fẹ́mi Akínṣọlá

Fẹ́mi Akínṣọlá

À ń pànà oko dà, áńbọ̀ǹtórí ọ̀nà ẹnu.
Ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti kéde ayípadà lórí ọjọ́ tí ilé ẹ̀kọ́ yóó di ṣíṣí padà káàkiri ìpínlẹ̀ náà.

Ọjọ́ Ajé tíí ṣe ọjọ́ kọkàndínlógbọ̀n oṣù kẹfà ni ìjọba Ṣèyí Mákindé ń gbèrò tẹ́lẹ̀ láti ṣí iléẹ̀kọ́ padà, àmọ́ Ìjọba ti so ó rọ báyìí nítorí bí àwọn èèyàn tó ń kojú Kofi-19 ṣe pọ̀ si nípìńlẹ̀ náà.

Akọ̀wé ìròyìn fún Gómìnà ìpínlẹ̀, Taiwo Adisa ló fi ìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀ fáwọn akọ̀ròyìn lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun.

Ní báyìí, àwọn olùkọ́ nìkan ni yóó wọlé padà lọ́jọ́ kọkàndínlógbọ̀n oṣù kẹfà nígbà táwọn akẹ́kọ̀ọ́ kan yóó wọlé padà lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ kan táwọn olùkọ́ wọn bá ti wọlé tán.

Ẹ̀wẹ̀, ìjọba àpapọ̀ ti kọ́kọ́ tako ṣíṣí ilé ẹ̀kọ́ padà lásìkò yìí tí àrùn Kòrónáfairọ̀ọ̀sì sì ń pọ̀ si ní Nàìjíríà, ìjọba ní àìka ìlera àwọn èèyàn sí ni.

Àmọ́ Ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ sọ pé òhun ti gbaradì fún ṣíṣí iléẹ̀kọ́ padà nípa ríran àwọn akọ́sẹ́mọsẹ́ nínú ètò ìlera àti ọ̀rọ̀ àyíká lọ sí àwọn ilé ẹ̀kọ́ láti sọ bí ètò ṣe le kẹ́sẹjárí.

Ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ní gbogbo ètò ló ti tò láti ríi pé àwọn olùkọ́ àtàwọn akẹ́kọ̀ọ́ ń tẹ̀lẹ́ ìlànà tí ìjọba là kalẹ̀ láti dènà ìtànkálẹ̀ arun Kofi-19.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo Ọrẹ …