Home ÀKỌ̀TUN Edo 2020; Obaseki kò kún ojú òsùwò̩n láti díje dupò ní PDP – Ilé-e̩jó̩
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - June 23, 2020

Edo 2020; Obaseki kò kún ojú òsùwò̩n láti díje dupò ní PDP – Ilé-e̩jó̩

Edo 2020; Obaseki kò kún ojú òsùwò̩n láti díje dupò ní PDP – Ilé-e̩jó̩

Yínká Àlàbí

Yoruba bo, won ni “ibere ija laa mo, ko seni to mo ipari re”.
Awuyewuye ibo si ipo gomina ni ipinle Edo nini osu kesan-an odun yii tun gba ona miran yo.
Sadede ni ile-ejo to fi ikale si ilu Benin da ejo ti okan ninu oludije du ipo gomina labe egbe oselu PDP Ogbeni Omoregie Ogbeide-Ihama pe, ile-ejo ni gomina Godwin Obaseki ko letoo lati dije du ipo gomina labe egbe oselu PDP.
Arakunrin naa pe ejo pe,o sese wa darapo mo egbe ni, o si fe dije du ipo gomina bee naa nigba ti awon kan ti to sile fun ipo naa, o ni eyi ko ba ofin egbe naa mu rara. O ni ki won fihan oun ninu iwe ofin egbe ti eniyan ti letoo lati darapo mo egbe ni ose yii, ki o si dije du ipo nla bii ipo gomina ni ose to telee.
Otunla, ojo Eti, ojo karundinlogbon, osu yii ni ibo abele fun ipo gomina egbe naa maa waye.
Oro oselu Naijiria to, to fun un, ko si ohun ti ko tun le sele ki o to di otunla naa. Eni to pejo le ni asise ni, ile-ejo miiran tun le ta ko ejo yii ki o to di otunla. Gbogbo bi o ba se n lo ni IROYIN OWURO maa fi to eyin ara ilu leti.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Adédoyin ṣépè fáwọn oníròyìn nílé ẹjọ́

Adédoyin ṣépè fáwọn oníròyìn nílé ẹjọ́ Ọrẹ Òtítọ́jù Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fáwọn oníròyìn láàárọ̀…