Home ÀKỌ̀TUN Ìròyìn òfegè ní pé wọ́n ti géètì mọ́ igbákejì mi— Akérédolú
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - June 22, 2020

Ìròyìn òfegè ní pé wọ́n ti géètì mọ́ igbákejì mi— Akérédolú

Ìròyìn òfegè ní pé wọ́n ti géètì mọ́ igbákejì mi— Akérédolú

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ọ̀rọ̀ ti di bí ará ilé è rẹ bá lẹ́nu, ìwọ náà ríi pé o ní ẹsẹ̀.
Ní báyìí,Gómìnà ìpínlẹ̀ Òǹdó Rotimi Akeredolu náà kò kúnu fèsì sí fídíò kan tó lu orí ayélujára pa, nínú èyí tí àwọn ẹ̀ṣọ́ kan ti dínà mọ́ ìgbákejì Gómìnà Òǹdó, Agboola Ajayi láti jáde kúrò nílé ìjọba.

Gómìnà Akérédolú sọ lójú òpó abẹ́yefò Twitter rẹ̀ pé, kò sí ohun kan tó lè mú òun sọ fáwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò láti dènà mọ́ ìgbákejì òun.

Lórí ẹ̀sùn pé Agboola fẹ́ fi ẹgbẹ́ òṣèlú APC sílẹ̀ lọ PDP, Akérédolú ní ìgbákejì òun le lọ sí ibi kíbi tó bá wù ú.

Gómìnà ìpínlẹ̀ Òǹdó ní àwọn kan ló kọ ìròyìn láti fi òun hàn gẹ́gẹ́ bí èèyàn burúkú.

Ohun tí a gbọ́ ni pé ààrin Akérédolú àti ìgbákejì rẹ̀ kò dán mọ́rán láti ìgbà tí Igbákejì kò ti dá sí àwọn ètò Ìjọba ìpínlẹ̀ Òǹdó kan, tó fi mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ilé ẹjọ́ tú el-zakzaky àti ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀

Ilé ẹjọ́ tú el-zakzaky àti ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀ Fẹ́mi Akínṣọlá Ajá tó relé ẹkùn tó bọ̀,ó tọ́ kí…