Home ÀṢÀ ÀTI ÌṢE Ó d’ọwọ́ àgbà, ó d’ọwọ́ èwe pẹ̀lú*
ÀṢÀ ÀTI ÌṢE - June 20, 2020

Ó d’ọwọ́ àgbà, ó d’ọwọ́ èwe pẹ̀lú*

*Ó d’ọwọ́ àgbà, ó d’ọwọ́ èwe pẹ̀lú*

*Àṣà àti ìṣe*

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ẹ̀yin àgbà bọ̀ ,ẹ móhùn bọnu pé ,báyé bá sèèsì tojú àgbà bàjẹ́, àìmọ̀wáhù wọn ni.

Hun hùn hún ! Ayé ò nán-án ní àṣà ńlẹ̀ yí mọ́, ohun olóhun ni wọ́n ń toṣọ mọ́ láa níbi gbogbo .

Báa bá sọ̀rọ̀, tẹ́nu kìí gbọ̀n wẹ̀hẹ̀rẹ̀wẹ̀ bí okùn dalẹ̀ bèbè níbàdí.

Ẹ jẹ́ á fiṣẹ́ yin àwọn àgbà T’órí dásí, ṣẹ́kù fúnwa nílẹ̀ yí.
Ẹ jẹ́ á tètè sàmúlò o wọn .

Àwọn laṣọ ìbora t’Èdùà sẹ́kù fúnwa bí ọ̀pá ìríran.

Òmùgọ̀ ní n tí ó gbà lọ́dọ̀ ọlọ́gbọ́n, ọlọ́gbọ́n ní n tí ó gbà lọ́dọ̀ òmùgọ̀.

èèyàn tó sọlénu, ló sàpò ìyà kọ́ .

Ẹ sàmójú kúrò àṣìṣe è mi, ibi àgbà t’ọ́mi dé rèé, ìròrí màjèṣìn ló pamí bí àjímu ògùrọ̀ níbi ẹ bá tí kà àròkàn mi débi àlèébù.

Ẹ̀mí gígùn, àlàáfíà lẹ ó fi kàmí-ìn.
ire o.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Rògbòdìyàn ẹgbẹ́ onímọ́tò Èkó n fẹ́jú kẹkẹ

Rògbòdìyàn ẹgbẹ́ onímọ́tò Èkó n fẹ́jú kẹkẹ Ọrẹ Òtítọ́jù Àwọn àgbà sọ pé ìjàngbọ̀n kìí nìka…