Home ÀKỌ̀TUN Èǹmò̩ wò̩lú! è̩sùn ìfipá-báni-lò lé è̩é̩dé̩gbè̩rin – Ò̩gá O̩ló̩pàá
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - June 20, 2020

Èǹmò̩ wò̩lú! è̩sùn ìfipá-báni-lò lé è̩é̩dé̩gbè̩rin – Ò̩gá O̩ló̩pàá

Èǹmò̩ wò̩lú! è̩sùn ìfipá-báni-lò lé è̩é̩dé̩gbè̩rin – Ò̩gá O̩ló̩pàá

Yínká Àlàbí

Oga olopaa patapata ni orileede yii, Ogbeni Adamu Mohammed lo n ba awon oniroyin soro laipe.
O ni konile o gbele to gbodo kan ti je ki iwa ibaje gbile bi owara ojo lawujo.
O ni lati osu keta ti gbogbo ile-iwe ti wa Nile, ti gbogbo osise naa wa nile, ni eyi ti o wa mu ki awon onisekuse maa ri ohun ti ko ye ki won ri, o je ki won raaye wo ohun ti ise ko ki n je ki won raaye wo tele.
Oga olopaa ni iyalenu nla lo je fun ago olopaa gan-an pe awon ti ri esun nipa ibani-lopo ati jijabale obinrin lona aito ti le ni eedegberin. O ni esun eedegberin le mejidinlogun (717) ni o ti de ago awon kaakiri orileede yii lati osu kin-in-ni titi di osu karun-un odun yii. O ni aimoye lo si n sele ti ko de ago awon.
Ago olopaa ni awon eniyan buruku yii soro lati mu fun ago olopaa nitori pe awon eniyan to n se ise ibi yii sun mo eni ti won n se ika yii fun gan-an.
Ago olopaa ni oro tiwon tun yato fun bi awon se n sode ole. Won soro lati mu nitori won n gbe pelu awon ti won n seka fun.
Oga olopaa ni ju gbogbo re lo, ki olomo obinrin kun fun amojuto to po lori awon omo won. Ki won je ki awon omo naa je ore won timo-timo paapaa julo awon mama.
Ogo olopaa ni oro esun ibanilopo daru de bi wi pe, baba n ba omobinrin re lo, o n waye laarin egbon ati aburu ki a ma sese wa so ti awon alajogbe ati aladugbo.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo Ọrẹ …