Home ÀKỌ̀TUN Obaseki gúnlẹ̀ sínú ẹgbẹ́ òṣèlú PDP
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - June 19, 2020

Obaseki gúnlẹ̀ sínú ẹgbẹ́ òṣèlú PDP

Obaseki gúnlẹ̀ sínú ẹgbẹ́ òṣèlú PDP

Fẹ́mi Akínṣọlá

Kángun kàngun kángun , ó di dandan kó sáà Kángun síbìkan, bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ lọ̀rọ̀ gómìnà ìpínlẹ̀ Edo Godwin Obaseki dà báyìí, bí ó tí sí kúrò ní ẹgbẹ́ òṣèlú onítẹ̀síwájú, All Progressive Party lọ sí ẹgbẹ́ òṣèlú People’s Democratic Party.

Akọ̀wé gómìnà Crusoe Osagie ló fìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀ fún akọ̀ròyìn.

Sáájú ni Obaseki ti kéde lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ kẹrindinlógún, oṣù kẹfà ọdún 2020 pé òun yóó kòwé fi ẹgbẹ́ òṣèlú APC silẹ̀ tẹ́lẹ̀.

Lósàn òní ni Gómìnà ìpínlẹ̀ Edo Godwin Obaseki tìkara rẹ̀ kéde nílé ẹgbẹ́ òṣèlú People’s Democratic Party (PDP) nílùú Benin pé òun ti di ọmọ ẹgbẹ́ náà.

Fọ́nran tó jẹyọ lójú òpó abẹ́yefò ,twitter ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ni gómínà ọ̀hún tí sọ pé, ní ìpínlẹ̀ Edo àti jákèjádò orílẹ̀ -èdè Nàìjíríà ní òun ti di ọmọ ẹgbẹ́ náà.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run Ọrẹ Òtítọ́jù Ayẹyẹ ọjọ́ọ̀bì à…