Home ÀKỌ̀TUN Ajímọ̀bi ò kú o, ẹ dákẹ́ àhesọ — ẹbí Ajímọ̀bi
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - June 19, 2020

Ajímọ̀bi ò kú o, ẹ dákẹ́ àhesọ — ẹbí Ajímọ̀bi

Ajímọ̀bi ò kú o, ẹ dákẹ́ àhesọ — ẹbí Ajímọ̀bi

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ọ̀rọ̀ òkèèrè, bí ò dín, yóó lé ní àwọn àgbà wí. Látàrí ariwo ràn-ìn téèéfín rẹ̀ bojú òpó ayélujára kan kan kan,ẹbí Gómìnà àná ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Sẹ́nétọ̀ Abíọ́lá Ajímọ̀bi ti jáde síta wá sọ pé irọ́ ni pé Ajímọ̀bi kú o.

Wọ́n ní àhesọ lásán ni ọ̀rọ̀ tó ń jà rànyìnrànyìn nílẹ̀ pé ìgbákejì Alága ẹgbẹ́ òṣèlú APC náà ti jáde láyé nípaṣẹ̀ àjàkálẹ̀ àrùn apinni léèmí Kòrónáfairọ̀ọ̀sì.

Fatima Ganduje Ajímọ̀bi, tó jẹ́ ọmọ Gómìnà Abdullahi Ganduje tó ń tukọ̀ ìpínlẹ̀ Kano, tó fẹ́ ọmọkùnrin Abíọ́lá Ajímọ̀bi fi ọ̀rọ̀ náà léde lójú òpó abẹ́yefò twitter rẹ̀ pé irọ́ ni.

Àhesọ yìí kò ṣẹ̀yìn in bí wọ́n ṣe kọ́kọ́ ń sọ ọ́ kiri pé Ajímọ̀bi ti lùgbàdi Kofi-19 tó sì ń gba ìtọ́jú nílé ìwòsàn aládàáni kan ní ìpínlẹ̀ Èkó.

Lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ kẹrìndínlógún, oṣù kẹfà yìí ni agbẹnusọ fún Sẹ́nétọ̀ Ajímọ̀bi, Ọ̀gbẹ́ni Bọ́lájí Túnjí ti kọ́kọ́ ṣọ̀rọ̀ lórí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí Ajímọ̀bi .

Ó ní Ajímọ̀bi ti sèlérí láti yanjú aáwọ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú APC lásìkò ìpàdé àpapọ̀ ẹgbẹ́ ti NEC tó ń bọ̀ lọ́nà.

Nínú àtẹjáde mìíràn tó fí ṣọwọ́ sí oníròyìn ní yàjóyàjó,agbẹnusọ Gómìnà lórí ọ̀rọ̀ tó jẹ́mọ́ ìròyìn, Ọ̀gbẹ́ni Bolaji Tunji tí ṣọ pé , òun tí gbọ́ sí àhesọ ọrọ kan tó ń ràn mọọ bí iná ẹẹrun pé Ọ̀gá òun jáde láyé, ó ní kí àwọn èèyàn tàkìtì ìpàkọ́ sí ìròyìn náà àti pé àwọn ń bẹ Ọlọ́run kò túbọ̀ lékún àánú Rẹ̀ lórí rẹ̀ fún ìlera pípé.
Ó wá dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn èèyàn fún àdúrà àti àdúrótì wọn.

Bákan náà ní Fatima tún dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn èèyàn tó ń pè láti bèèrè nípa Bàbá wọn Ajímọ̀bi.
Ó kádìí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé kò sí ẹni tí kò ní kú lọ́jọ́ kan ṣùgbọ́n ẹbí Ajímọ̀bi ń dúpẹ́ pé ó ṣì wà láàyè.

Hun hùn hún! À fi kí Ọlọ́run sàánú wa nínú àwùjọ yìí.

Ìlòkulò òògùn la tí ń gbọ́ tẹ́lẹ̀ tó gbayé kan ,ìlòkulò àbaàdì ìròyìn látàrí àsìlò àǹfààní ẹ̀rọ ìkànsíraẹni,fesibúùkù, Tẹ́lígíràmù, Sítágíràmù, abẹ́yefò, abánidọ́rẹ̀ẹ́ ojú kojú, wàsáàpù àti àwọn míì tí wá fara pẹ́ ìlòkulò òògùn ajániláyà pàtì fẹ́ ẹ̀ méèmí ẹni lọ báyìí pẹ̀lú bí bọ̀kílẹ̀ àwọn ìròyìn yàjóyàjó wọ̀nyí ṣé máa ń jẹ́ òfegè.
Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ẹ léèyàn kú, ẹbí lẹ́ni àwọn kù.
Ẹ jẹ́ á gbìyànjú yẹra wa wò fún àtúnṣe kí Orílẹ̀ yìí le ní ìfọ̀kànbalẹ̀.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run Ọrẹ Òtítọ́jù Ayẹyẹ ọjọ́ọ̀bì à…