Home ÀKỌ̀TUN L’ẹ́gbẹ́ òṣèlú APC; alága méjì lójijì lalẹ̀ hù—- Ajimobi àti Victor Giadom
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - June 18, 2020

L’ẹ́gbẹ́ òṣèlú APC; alága méjì lójijì lalẹ̀ hù—- Ajimobi àti Victor Giadom

L’ẹ́gbẹ́ òṣèlú APC; alága méjì lójijì lalẹ̀ hù—- Ajimobi àti Victor Giadom

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn àgbà bọ̀ wọ́n ní bí ọ̀rọ̀ ńlá kò bá tí ì tán, èèyàn ńlá kò níí sinmi àròyé.
Sinimọ́ oríta sì ń tẹ̀síwájú pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tó jẹ mọ́ yíyàn ọmọ oyè nínú ẹgbẹ́ òṣèlú náà.
Ìròyìn míì tó jọ eré oníṣẹ ti ń fi yé ni pé, ìgbákejì Akọ̀wé àpapọ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú APC, Victor Giadom ti bọ́ s’órí oyè gẹ́gẹ́ bíi adelé Alága àpapọ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú náà.

Ọ̀rọ̀ ti di iṣu ata yán-an-yàn-an lẹ́gbẹ́ òṣèlú APC báyìí pẹ̀lú bí ẹgbẹ́ òṣèlú ọ̀hún ṣe ń ní adelé Alága àpapọ̀ méjì láàrin wákàtí díẹ̀ sí ara wọn.

Ní kété tí ilé ẹjọ́ pàṣẹ kí Adams Oshiomole ó fi ipò sílẹ̀, ni ẹgbẹ́ òṣèlú APC ti kéde Sẹ́nétọ̀ Abíọ́lá Ajímọ̀bi gẹ́gẹ́ bí adelé Alága àpapọ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú náà.

Àmọ́ ṣá, kò pẹ́ púpọ̀ ni ẹni tó jẹ́ ìgbákejì Akọ̀wé àgbà ẹgbẹ́ òṣèlú ọ̀hún, Victor Giadom jáde sí bọnbọ pẹ̀lú ìwé ìdájọ́ láti Ilé ẹjọ́ kan , eléyìí tó ní òun ni ó tọ́ sí láti di ipò náà mú.

Ní Ọjọ́rú sì ni Gaidom gun orí àga náà gẹ́gẹ́ bí adelé Alága àpapọ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú APC.

Ní wàràǹsesà tí ó wọlé ni ó ti kéde pé òun ń gba àkóso ní ìbámu pẹ̀lú ìdájọ́ Ilé ẹjọ́ tó ní ó fún òun lágbára àti ṣe bẹ́ẹ̀.

Bákan náà ló wọ́gilé ètò àyẹ̀wò àwọn olùdíje fún ipò gómìnà lábẹ́ àṣìá ẹgbẹ́ òṣèlú APC ní Ìpínlẹ̀ Edo.

Ó fi kún un pé gbá-gbá gbá làwọn ọmọ ìgbìmọ̀ májẹ̀óbàjẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú náà wà lẹ́yìn òun lórí ìgbésẹ̀ náà.
Kò sí àníànì, ọ̀rọ̀ yìí kò le parí síbẹ̀, bí ó bá se ń lọ, a o máa jábọ̀ fún un yín.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu

Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu Ọrẹ Òtítọ́jù Olùdíje fún i…