Abiola Ajimobi ni Alága ẹgbẹ́ òṣèlú APC — Àjọ amúṣẹ́yá (NWC)
Abiola Ajimobi ni Alága ẹgbẹ́ òṣèlú APC — Àjọ amúṣẹ́yá (NWC)
Fẹ́mi Akínṣọlá
Àjọ Amúṣẹ́yá ẹgbẹ́ òṣèlú APC, NWC ti kéde Sẹ́nétọ̀ Abíọ́lá Ajímọ̀bi gẹ́gẹ́ bí Alága ẹgbẹ́ tuntun ní Ìlà Oòrùn orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
Èyí kò sèyìn ìdájọ́ iléẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn ní ìlú Àbújá tó fi óntẹ̀ lù ú pé kí wọ́n yọ Adam Oshiomọlẹ gẹ́gẹ́ bí Alága ẹgbẹ́ òṣèlú náà.
NWC fi léde pé ní ìtẹ̀lé ìdájọ́ Iléẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn ló mú kí àwọn gbé ìgbésẹ̀ náà lọ́nà tó bá òfin ẹgbẹ́ mu.
Àmọ́, ní báyìí ohun tí àwọn ènìyàn ń sọ ni pé Sẹ́nétọ̀ Abíọ́lá Ajímọ̀bi wà ní ìdùbúlẹ̀ àìsàn láti bíi oṣù díẹ̀ sẹ́yìn.
Bákan náà, àwọn ènìyàn tó ń fi èrò wọn hàn lórí ẹ̀rọ ìkànsíraẹni abẹ́yefò Twitter ní kò yẹ kí ẹgbẹ́ òṣèlú APC fi ẹni tó wà lórí ìdùbúlẹ̀ àìsàn ṣe Alága ẹgbẹ́ papà jùlọ , nírú àsìkò tí ìdìbò ń bọ̀ lọ́nà ní ìpínlẹ̀ Òǹdó àti Edo.
Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu
Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu Ọrẹ Òtítọ́jù Olùdíje fún i…