Home ÀKỌ̀TUN Ẹ tẹ̀lé òfin sísí llé ẹ̀kọ́, Sọ́ọ̀ṣì àti Mọ́sálásí l’Ọ̀yọ́– Ṣèyí Mákindé
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - June 16, 2020

Ẹ tẹ̀lé òfin sísí llé ẹ̀kọ́, Sọ́ọ̀ṣì àti Mọ́sálásí l’Ọ̀yọ́– Ṣèyí Mákindé

Ẹ tẹ̀lé òfin sísí llé ẹ̀kọ́, Sọ́ọ̀ṣì àti Mọ́sálásí l’Ọ̀yọ́– Ṣèyí Mákindé

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé kò sí n tíí ní ìbẹ̀rẹ̀ tópin kìí dé bá, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé díẹ̀ díẹ̀ ni, síbẹ̀, ọ̀nà àbáyọ ń wà sí àwọn ìpèníjà tí ó ń kojú Orílẹ̀ yìí lásìkò táa wà yìí, èyí tí kò yọ ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ sílẹ̀.

Ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lábẹ́ àkóso Gómìnà Onímọ̀ ẹ̀rọ Ṣèyí Mákindé ti gbé ìgbésẹ̀ pé kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ìwé kẹfà níléèwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ (Primary Six), ìwé kẹta ilé-ẹ̀kọ́ girama kékeré (JSS 3) àti kíláàsì àṣekágbá ilé- ẹ̀kọ́ girama (SSS 3) nìkan ni yóó wọlé báyìí sí yàrá ìkẹ́kọ̀ọ́ ní ọjọ́ náà ti wọn sì gbọdọ̀ máa tẹ̀lé àwọn Ìlànà tí ìgbìmọ̀ amúṣẹ́yá náà bá fi sílẹ̀.

Bákan náà ló tún fi kún-un pé àwọn iléèjọsìn pẹ̀lú leè padà sí níí ṣí ìlẹ̀kùn wọn sílẹ̀ fún ìjọsìn láti ọjọ́ Ajé kan náà ṣùgbọ́n ìdá kan nínú mẹ́rin àwọn èèyàn tó ń wá sí iléèjọsìn náà tẹ́lẹ̀rí ni ààyè gbà láti máa jọ́sìn fún àsìkò yìí ná, tí wọ́n sì gbọdọ̀ tẹ̀lé òfin àti ìlànà ìgbìmọ̀ amúṣẹ́yá náà.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Àwọn wọ̀nyí ti kékeré dèrò ẹ̀wọ̀n, jìbìtì orí ayélujára ló kó bá wọn

Àwọn wọ̀nyí ti kékeré dèrò ẹ̀wọ̀n, jìbìtì orí ayélujára ló kó bá wọn Ọrẹ Òtítọ́jù Àwọn ló …