Home ÀKỌ̀TUN Ọ̀gá Ọlọ́pàá , túkùn lọ́rùn àwọn ẹ̀ṣọ́ mi –Aisha Buhari fọhùn
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - June 15, 2020

Ọ̀gá Ọlọ́pàá , túkùn lọ́rùn àwọn ẹ̀ṣọ́ mi –Aisha Buhari fọhùn

Ọ̀gá Ọlọ́pàá , túkùn lọ́rùn àwọn ẹ̀ṣọ́ mi –Aisha Buhari fọhùn

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ọ̀gá àgbà àwọn ọlọ́pàá Nàìjíríà ti kọ̀ láti dá ìyàwó Ààrẹ Orílẹ̀ yìí , Aisha Buhari lóhùn láti ìgbà tó ti ṣọ fún un lọ́jọ́ Ẹtì pé kó tú àwọn ẹ̀ṣọ́ rẹ̀ sílẹ̀ láhàámọ́ ọlọ́pàá.

Èyí ń ṣẹlẹ̀ látàrí bí Ìròyìn ṣe ní ìyàwó àti àwọn ọmọ Ààrẹ ṣe gbógun ti akọ̀wé pàtàkì sí Ààrẹ Yusuf Sabiu ọmọ ẹ̀gbọ́n Ààrẹ, tí wọ́n fún ní àlàjẹ́ Tunde.

Àwọn ìwé Ìròyìn kan jábọ̀ pé títí di agogo mẹ́rin ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ àbámẹ́ta, wọ́n ṣì wà láhàámọ ọlọ́pàá.

Wọ́n ní ará ilé Ààrẹ kan ló ta àwọn lólobó pé Tunde ṣẹ̀ṣẹ̀ dé láti ìpínlẹ̀ míì ni, ó sàbẹ̀wò sí olùdarí iléeṣẹ́ ìpọnpọ NNPC, Maikanti Baru tó ṣẹ̀ṣẹ̀ kú nípaṣẹ̀ Kofi-19. Wọ́n ní ó tún sàbẹ̀wò sáwọn ibòmíìn.

Dípò kó lọ ya ara rẹ̀ ṣọ́tọ̀ gẹ́gẹ́ bí òfin, wọ́n ní ń ṣe ló pinnu láti darí sí Aso Rock tó sì mọ̀ pé òun jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó Máa ń súnmọ́ Ààrẹ.

Ọ̀rọ̀ yìí ló dà bíi pé ó fa sábàbí gan an tí ìyàwó Ààrẹ fi fi sójú òpó abẹ́yefò Twitter rẹ̀ pé ó yẹ kí ọwọ́ òfin tẹ ẹni tó bá rúfin má rìn lásìkò ìṣéde yìí.

“Ààrẹ Buhari ti súnmọ́ ọgọ́rin ọdún ò sì le wà ní bèbè àìsàn tó bá ń ràn.

A ní kí Tunde má wọlé àfìgbà tó fipá wọlé tó tún fi ọlọ́pàá mú àwọn ẹ̀ṣọ́ Aisha tí kò fẹ́ kó wọlé”. Àwọn kan ní ó ti fẹ́ máa ní irú ìbáṣepọ̀ tó wà láàrin Ààrẹ àti olórí àwọn òṣìṣẹ́ Ààrẹ tẹ́lẹ̀rí, Abba Kyari.

Ẹ̀wẹ̀, Aisha ní kí wọ́n tú àwọn ẹ̀ṣọ́ òun sílẹ̀, kí wọ́n má sí wọn sílẹ̀ sí àrùn Kòrónáfairọ̀ọ̀sì.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo Ọrẹ …