Home ÀKỌ̀TUN Gbogbo ayé máa mo̩ ibi tí mò ń lo̩ lé̩yìn ìpàdé pè̩lú Buhari – Obaseki
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - June 15, 2020

Gbogbo ayé máa mo̩ ibi tí mò ń lo̩ lé̩yìn ìpàdé pè̩lú Buhari – Obaseki

Gbogbo ayé máa mo̩ ibi tí mò ń lo̩ lé̩yìn ìpàdé pè̩lú Buhari – Obaseki

Yínká Àlàbí

Lati igba ti egbe oselu APC ti fi oselu han gomina ipinle Edo, Ogbeni Godwin Obaseki ni ko ti mo “odo ti o maa da orunla re si”.
O ti se ipade pelu gomina ipinle Rivers, Ogbeni Nyesom Wike ati ti ipinle Akwa Ibom, Ogbeni Udom Emmanuel. Egbe oselu PDP ni awon gomina yii wa bee naa ni iroyin gbee pe ipade kikan kikan naa n lo pelu egbe oselu SDP.
Awon oniroyin ko je ki gomina yii gbadun, ni eyi ti o je ki o dahun pe ki a fun oun ni ojo die nitori pe oun ti seto ipade pelu Aare Mohammadu Buhari.
O ni leyin ipade yii ni oun to maa mo eyi ti oun maa se.
Ti a ko ba gbagbe, iwe eri ni won fi ja gomina Obaseki pe ko kun oju osuwon to lati te siwaju gege bii gomina ipinle Edo. Iwe eri yii kan naa ni o fi tuko odun merin to n tan yii. Ni eyi ti o tumo si pe, “enu ti aye fi n pe ade gun naa ni won fi n pe ade ko gun”.
Awon agba kan tile ni ija lo de lorin dowe, won ni aifagba fenikan Obaseki lo yoo kuro legbe. Won ni o n foju baba isale gbole.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Jàndùkú ya wọ iléeṣẹ́ rédíò Amúlùúdùn n’Íbàdàn, wọ́n ba ọ̀pọ̀ dúkìá jẹ́

Jàndùkú ya wọ iléeṣẹ́ rédíò Amúlùúdùn n’Íbàdàn, wọ́n ba ọ̀pọ̀ dúkìá jẹ́ Ọrẹ Òtítọ́jù Òkú k…