Home ÀKỌ̀TUN Prophet tó ń s̩e ìwòsàn covid-19 kú ikù covid-19
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - June 14, 2020

Prophet tó ń s̩e ìwòsàn covid-19 kú ikù covid-19

Prophet tó ń s̩e ìwòsàn covid-19 kú ikù covid-19

Yínká Àlàbí

Yoruba bo, won ni “iku ogun ni pa akinkanju, iku odo ni pa omuwe” ni eyi to tumo si pe o seese ki eniyan ku iku ise to yan laayo.
Alagba Franklin Ndifor ni okan ninu awon ojise Olorun ti orileede Cameroon. Oun ni o ni arun covid-19 ko koja agbara ti oun ni.
Eyi mu ki o bere si ni maa gbowo le awon eniyan lori kaakiri, ti awon kan si ni iwosan n de si awon. Bi awon eniyan se bere si ni wo bi omi lo si ile ijosin alagba yii niyi.
Ko ju osu kan lo ti alagba naa bere si ni sinto, wuko titi ti ko fi le mi daadaa mo. Awon omo ijo ba bere adura kikan-kikan, pe alagba awon ko gbodo ku.
Nigba ti awon dokita oyinbo fi maa de ibe, “epa ko boro mo”. Awon dokita ni won ti pe sii, eni ti mimi re ko Jake lati bii ose kan ti e de mole ti e wa n gbadura si. Awon dokita ni “aso ko bomoye mo, omoye ti rin ihoho woja”.
Iku Pasito yii dun awon eniyan kan nitori pe o je eni ti awon eniyan feran, o rewa lokunrin,koda awon ara ilu gbee kale fun ipo Aare orileede Cameroon ni odun 2018 ki o to fidi remi. Ipo kefa lo se ni orileede naa.
Oloogbe Franklin ko ju omo odun mokandinlogoji (39 year)lo ki iku to poju re de. Awon onimo ilera ni pelu ojo ori re, ki ba ye ajakale arun naa ka ni won tete gbe lo si ile iwosan.
Kayefi ni iku Alagba naa je fun ijo, won ko tete gba pe o ti lo je ipa awon baba nla re. Awon omo ijo ba ijoba ja pe ko ye ki won tete sin oku re nitori pe bi o se dake yen, o le wa ninu emi pelu Oluwa. Won ni ijoba ki ba je ki awon wo oju re fun bii ojo meji sugbon ijoba orileede naa ko awon olopaa lo, won si fi taju-taju le awon omo ijo naa seyin ki won to le ri oku Oloogbe Franklin gbe lati lo sin si ibi ti won n toju oku arun covid-19 si. “Aisan lo see wo, a ko ri ti olojo se”.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu

Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu Ọrẹ Òtítọ́jù Olùdíje fún i…