Home ÀKỌ̀TUN Agbègbè Akínyẹlé níbàdàn ti di bùba ẹrù jẹ̀jẹ̀ t’ọ́daràn tí ń yan fanda
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - June 14, 2020

Agbègbè Akínyẹlé níbàdàn ti di bùba ẹrù jẹ̀jẹ̀ t’ọ́daràn tí ń yan fanda

Agbègbè Akínyẹlé níbàdàn ti di bùba ẹrù jẹ̀jẹ̀ t’ọ́daràn tí ń yan fanda

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ẹnu kò fẹ́ sìn lára afọ́kéèmù àwọn kọ̀lọ̀rànsí ọ̀daràn Akínyẹlé àti agbègbè rẹ̀ báyìí o, bí wọ́n se ń kéwọn lọ́wọ́ bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń ki òrùka bọ̀ ọ́.

Agbófinró ń gbìyànjú, ọ̀daràn ń sẹ́bùrú èrò mọ́ wọn lọ́wọ́ gbilẹ̀ nínú ìbàjẹ́.

Bí kò bá wa rí bẹ́ẹ̀, ìgbà wo ni gbogbo agbègbè tí à n ṣọ yìí sí kan gbínríngbínrín ná fún omijé lójú tẹbí tará , tọ rẹ̀ tí wọ́n sì ń sunkú àsungbà lórí ti Barakat Bello àti alábóyún oṣù méje tí wọ́n fòkúta fọ́ lórí yọ ọlẹ̀ inú rẹ̀ lọ.

Àjáàbalẹ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ ajániláyà pàtì méèmí ẹni gbọ̀n jìnìjìnì míì ló tún wáyé lágbègbè yìí kan náà.

Ọmọbìnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Grace Oshiagwu jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ tó wà ní ọdún kínní nílé ẹ̀kọ́ gbogboǹṣe Òkè Ògùn.
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ fún akọròyìn nílùú Ìbàdàn lọ́jọ́ Àbámẹ́ta.

Ní Ilé oníwáàsù ìjọ CAC kan tó wà ní Orí Sásá Ọ̀jọ́ọ̀ lágbègbè Akínyẹlé ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé.
Ìwádìí fihàn pé baba ọmọbìnrin yìí gán an ni pásítọ̀ sọ́ọ̀sì ọ̀hún.

Ohun tí a gbọ́ ni pé Grace wà pẹ̀lú ẹ̀gbọ́n rẹ̀ àtàwọn ọmọ ìjọ mìíràn tí wọ́n wá kọ́ jìtá ní sọ́ọ̀sì.

Wọ́n ní ṣàdédé ni Grace dìde kúrò láàrin wọn láti lọ rẹjú díẹ̀ nínú ilé oníwáàsù tí ẹbí rẹ̀ ń gbé.

Ìtẹ̀síwájú ìròyìn náà fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé, nígbà tí ẹ̀gbọ́n rẹ̀ náà dìde kúrò láàrin àwọn tí wọ́n jọ ń kọ́ jìtá ló bá Grace níhòòhò tí ipọ́n sì b ò ó dáru.

Nígbà tó ń fọhùn tomijé tomijé lójú, Adelé Alága Agbègbè onídàgbàsókè Gúúsù Akínyẹlé,
Ọnarébù Kazeem Bolarinwa sàlàyé pé,o kọjá ojú tí àwọn èèyàn fi n wo ọ̀rọ̀ náà pé ìfipábánilò ni .

Ó ní níwòye t’òun, àwọn afini ṣètùtù ọ̀la ni, tí wọ́n kàn n fi ìbálòpọ̀ se bojú bojú láti gbójú àwọn èèyàn ìlú kúrò nínú ìwà láabi wọn.
Ẹlòmíì tó lọ sí ibi ìṣẹ̀lẹ̀ náà tiẹ̀ sọ pé ìbo abẹ́ tí Grace wọ̀ ti ya pútupùtu.

Akẹ́kọ́ọ̀bìnrin yìí ni a gbọ́ pé ó pàdánù ìyá a rẹ̀ ni ọdún díẹ̀ sẹ́yìn, bákan náà ni bàbá rẹ̀ ti lé ní ọgọ́ta ọdún.

Gbọmọgbọmọ ìṣẹ̀lẹ̀ kabiyamọ o máa fojú sunkú yìí ti wá fẹ́ ẹ̀ di bárakú àwùjọ báyìí, dẹbíi pé kò ní àsìkò kan pàtó mọ, àtàárọ̀ ,atọ̀sán , àtòru làwọn oníṣẹ́ ibi ń yan fanda.

À fi kí Ọlọ́run nínú Àánú Rẹ̀ ó dáàbò bòwá àti ẹbí wà níbi gbogbo lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá ìlú wọ̀nyí.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ilé ẹjọ́ tú el-zakzaky àti ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀

Ilé ẹjọ́ tú el-zakzaky àti ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀ Fẹ́mi Akínṣọlá Ajá tó relé ẹkùn tó bọ̀,ó tọ́ kí…