Home ÀKỌ̀TUN Obaseki ti d’ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, Irọ́ funfun— Ologbondiyan
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - June 13, 2020

Obaseki ti d’ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, Irọ́ funfun— Ologbondiyan

Obaseki ti d’ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, Irọ́ funfun— Ologbondiyan

Fẹ́mi Akínṣọlá

Kángun kàngùn kángun, yóó kúkú padà kángun síbìkan náà ni, bó pẹ́ , bó yá.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Alukoro ẹgbẹ́ òṣèlú náà( PDP), Kola Ologbondiyan ti ṣọ nínú ìfọ̀rọ̀wérọ̀ pẹ̀lú akọ̀ròyìn pé, irọ́ funfun báláú ni ìròyìn tó tàn kálẹ̀ káàkiri lórí ayélujára pé Gómìnà ìpínlẹ̀ Ẹdó, Godwin Obaseki ti darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP.

Ṣaájú ni ìgbìmọ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú APC tó ń ṣàyẹ̀wò àwọn olùdíje nípìńlẹ̀ Ẹdó ti yọ ọ́ kúrò lára àwọn olùdíje fún ipò gómìnà nínú ìdìbò abẹ́lé tó ń bọ̀.

Ṣùgbọ́n Obaseki ti sọ pé òun kò ní pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn lórí ìgbésẹ̀ ìgbìmọ̀ náà.

Ẹ̀wẹ̀, Ologbondiyan ní àwọn Ìlànà kan wà tí èèyàn ní láti tẹ̀lé kí ó tó le darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú alábùradà, PDP.

Ó ní àti Wọ́ọ̀dù lèèyàn ti le darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́, àti pé Alága ẹgbẹ́ PDP nípìńlẹ̀ Ẹdó kò sọ ohun tó jọ bẹ́ẹ̀ f’óun nígbà táwọn méjéèjì ń fọ̀rọ̀ jomitoro ọ̀rọ̀.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu

Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu Ọrẹ Òtítọ́jù Olùdíje fún i…