Home ÀKỌ̀TUN Mi ò ní pẹjọ́ tako bí APC ṣe múmi kúrò lára olùdíje abẹ́nú—Obaseki
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - June 13, 2020

Mi ò ní pẹjọ́ tako bí APC ṣe múmi kúrò lára olùdíje abẹ́nú—Obaseki

Mi ò ní pẹjọ́ tako bí APC ṣe múmi kúrò lára olùdíje abẹ́nú—Obaseki

Fẹ́mi Akínṣọlá

Egbìnrìn ọ̀tẹ̀ bí a ṣe ń pàkan l’òmí-ìn ń rú tú ú bíi iná ẹẹrun lọ̀rọ̀ àwọn olóṣèlú wa wọ̀nyí. Àtàrí wọn ni wọ́n ń fi gbogbo ọjọ́ ayé dù, wọn ò gbèrò báyé àwọn tí wọ́n ń ṣèlú lé lórí náà yóó ti ẹ̀ ṣe bẹ́súẹ́. Dípò o bẹ́ẹ̀, làpá ni wọ́n ń wò, wọ́n fi ẹ̀tẹ̀ baba làpá sílẹ̀ láì tọ́jú.
Bí mẹ̀kúnù bá ń tòògbé, kí Aláwùràbí Ó ṣá à má jẹ́ kí Ẹlẹ́dàá wọn sùn fọnfọn.

Gómìnà ìpínlẹ̀ Edo, Godwin Obaseki ti tako ìgbésẹ̀ ìgbìmọ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú APC tó ń sàyẹ̀wò àwọn olùdíje nípìńlẹ̀ Ẹdó tí wọ́n yọ ọ́ kúrò lára àwọn ọmọ oyè tí yóó díje fún ipò Gómìnà nínú ìdìbò abẹ́lé tó ń bọ̀.

Ṣùgbọ́n Obaseki ní òun kò ní pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn lórí ìgbésẹ̀ ìgbìmọ̀ náà.

Ohun tí wọ́n sọ ni pé kùdìẹ̀kudiẹ sì wà nínú àwọn ìwé ẹ̀rí rẹ̀ tó fi mọ́ ìwé ẹ̀rí àgùnbánirọ̀ rẹ̀.

Nínú àtẹjáde tí Obaseki fi síta lọ́jọ́ Ẹtì nípaṣẹ̀ olùrànlọ́wọ́ rẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ ìròyìn, ó ṣàlàyé pé kò ní ìtumọ̀ tí òun bá ní kí òun pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn.

Ó fikún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé bí wọ́n ti yọ òun kúrò nínú àwọn olùdíje ìbò abẹ́lé fún ìdìbò Gómìnà ìpínlẹ̀ Ẹdó kò sẹ̀yìn bí Alága àpapọ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú APC, Adams Oshiomhole ti sọ pé òun ní iléẹjọ́ tó ga jùlọ nínú ẹgbẹ́ náà.

Ó ní ohun ìtìjú ńlá gbàá ló ń ṣẹlẹ̀ nínú ẹgbẹ́ òṣèlú APC lábẹ́ Álága Oshiomole.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Nítorí ẹ̀sùn ìfipábánilòpọ̀, àwọn aláṣẹ Fásitì KWASU lé olùkọ́ kan dànù

Nítorí ẹ̀sùn ìfipábánilòpọ̀, àwọn aláṣẹ Fásitì KWASU lé olùkọ́ kan dànù Ọrẹ Òtítọ́jù Àwọn …