Home ÀKỌ̀TUN Ẹ̀yin tẹ́ ẹ r’òkìrìkà l’Ọ́jà Ọba Àkúrẹ́, ẹ lọ ṣàyẹ̀wò àrùn Kofi -19 — Akérédolú
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - June 13, 2020

Ẹ̀yin tẹ́ ẹ r’òkìrìkà l’Ọ́jà Ọba Àkúrẹ́, ẹ lọ ṣàyẹ̀wò àrùn Kofi -19 — Akérédolú

Ẹ̀yin tẹ́ ẹ r’òkìrìkà l’Ọ́jà Ọba Àkúrẹ́, ẹ lọ ṣàyẹ̀wò àrùn Kofi -19 — Akérédolú

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ẹni ikú fínú fíndọ̀ pa kò tó nǹkan, ẹni àìgbọ́n gbẹ̀mí ẹ̀ ló lọ súàdàdà.
Onílé yìí o ò tìlẹ̀kùn , tara rẹ̀ ni wọ́n kúkú ń lọ̀ ọ́ fún.

Níbá yìí Gómìnà ìpínlẹ̀ Òǹdó, Rotimi Akérédolú ti n ké tantan pàrọwà sáwọn èèyàn tó lọ ra aṣọ àlòkù ní Ọjà Ọba ìlú Àkúrẹ́ láìpẹ́ yìí láti lọ ṣe àyẹwò àrùn Kòrónáfairọ̀ọ̀sì o, ki nǹkan tó bọ́wọ́ s’órí.

Akérédolú ló ṣọ ọ̀rọ̀ náà nígbà tó ń jábọ̀ ibi iṣẹ́ dé dúró lórí ọ̀rọ̀ Kofi-19 ní ìpínlẹ̀ ọ̀hún.

Ìkéde yìí ló wáyé lẹ́yìn tí obìnrin kan tó ní àrùn náà ṣá kúrò nílé ìtọ́jú àwọn alárùn kòrónáfairọ̀ọ̀sì.

Lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀ tí àwọn agbófinró ti ń wá obìnrin náà ni ọwọ́ tẹ̀ẹ́ ní Ọjà Ọba níbi tó ti ń ta aṣọ ‘Òkìrìkà’ láàrin ìlú Àkúrẹ́.

Akérédolú tún sọ lójú òpó abẹ́yefò Twitter rẹ̀ pé ” A rọ àwọn ará ìlú tó ti lọ ra aṣọ àlòkù ní Ọjà Ọba, níbi tí a ti mú ẹni kẹtalelógójì tó ní àrùn Kofi -19 láti pèsè ara wọn fún àyẹ̀wò ní kíá kíá.”

Gómìnà ọ̀hún ní ìgbésẹ̀ yìí ṣe pàtàkì fún àǹfànì ara wọn àti fún gbogbo ará ìlú lápapọ̀.

Ó ní ìrọ̀rùn igi ,ni ìrọ̀rùn ẹyẹ.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ilé ẹjọ́ tú el-zakzaky àti ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀

Ilé ẹjọ́ tú el-zakzaky àti ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀ Fẹ́mi Akínṣọlá Ajá tó relé ẹkùn tó bọ̀,ó tọ́ kí…