Home ÀKỌ̀TUN Àwọn àǹjàǹnú ń gbowó oṣù l’ájọ Sùbẹ́ẹ̀bù Kwara- EFCC
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - June 13, 2020

Àwọn àǹjàǹnú ń gbowó oṣù l’ájọ Sùbẹ́ẹ̀bù Kwara- EFCC

Àwọn àǹjàǹnú ń gbowó oṣù l’ájọ Sùbẹ́ẹ̀bù Kwara- EFCC
Fẹ́mi Akínṣọlá

Àjọ tó ń gbógun ti ìwà jẹgúdújẹrá lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà EFCC sọ pé àṣírí àwọn ayédèrú òṣìṣẹ́ ẹgbẹ̀rún kan àjọ tó ń ṣàkóso ètò ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ nípìńlẹ̀ Kwara ti tú sí àwọn lọ́wọ́.

Orúkọ àwọn ayédèrú òṣìṣẹ́ yìí làwọn kan gb’ọ̀nà ẹ̀bùrú fi sínú orúkọ àwọn tó ń ṣiṣẹ́ tí wọ́n sì ń lu owó oṣù wọn ní póńpó.

Olórí àjọ náà tó ń bójú tó ẹ̀ka ìpínlẹ̀ Kwara ló fi ọ̀rọ̀ yìí tó àwọn oníròyìn létí nílù Ilọrin lọ́jọ́bọ.

Ọ̀gbẹ́ni Isyaku Sharu sọ pé nínú àwọn tí àwọn mú láti wá wí tẹnu wọn lórí ọ̀rọ̀ yìí ni Akọ̀wé àgbà kan àti Olùdarí iléeṣẹ́ Ìjọba lábẹ́ Ìjọba ìpínlẹ̀ Kwara kan náà wà.

Lójú òpó abẹ́yefò Twitter Efcc bákan náà ni wọ́n fi síbẹ̀ pé, àwọn ti rí owó tó tó mílíọ̀nù méjìdínlógóje náírà gbà padà lọ́wọ́ àwọn tó ku owó ọba ní póńpó.

Ó tún fikún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé àwọn tí ṣaájú dá àwọn owó kan t’áwọn rí gbà padà fún Gómìnà Kwara, Abdulrahman Abdurazaq

Àjọ Sùbẹ́ẹ̀bù ló yẹ kí ó má mójútó ọ̀rọ̀ ètò ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ní Kwara ṣùgbọ́n, ẹnu kò sìn lẹ́yìn àjọ náà pẹ̀lú bí àwọn olùkọ́ kò se rí owó oṣù gbà déédé, tí àwọn ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ kò sì wà nípò to wú ni lórí.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Okorocha ketí ikún sí ìpé làwọn fi ṣígun kàá mọ́lé mọ́lé-EFCC

Wọ́n ní Okorocha ketí ikún sí ìpé làwọn fi ṣígun kàá mọ́lé mọ́lé Ọrẹ Òtítọ́jù Àjọ tó ń gbó…