Home ÀKỌ̀TUN Ọkọ mi kò kú, ó ń palẹ̀ mọ́ ọjọ́ ìbí i rẹ̀ – Joke Jacobs
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - June 11, 2020

Ọkọ mi kò kú, ó ń palẹ̀ mọ́ ọjọ́ ìbí i rẹ̀ – Joke Jacobs

Ọkọ mi kò kú, ó ń palẹ̀ mọ́ ọjọ́ ìbí i rẹ̀ – Joke Jacobs

Fẹ́mi Akínṣọlá

Irọ́ ikú níí wọ́n-ọ́n pa á mọ́ ọkọ́,
Irọ́ ikú níí wọ́n-ọ́n pa á mọ́ àdá.
Irọ́ ikú níí wọ́n-ọ́n pa á mọ́ ilẹ̀.
Olú Jacobs, kò kú o. Ẹ wá míì ṣọ.

Ìrọ̀lẹ́ Ọjọ́rú ni ariwo ta pé gbajúgbajà òṣèré tíátà kan ní èdè Yorùbá àti òyìnbó, Olu Jacobs, ti jáde láyé.

Ìgbà kejì rèé ní ààrin oṣù kan tí Ìkéde yóó wáyé pé ilumọọka òṣèré tíátà náà papòdà, bẹ́ẹ̀ ní ọ̀pọ̀ èèyàn tó sì gbọ́ Ìkéde yìí ló ká ọwọ́ s’órí pé ẹni re lọ.

Ṣùgbọ́n ìwádìí ìròyìn ti fihàn pé àhesọ ọ̀rọ̀ àti irọ́ ńlá tó jìnà sí òótọ́ ni ìkéde náà, nítorí Olu Jacobs sì wà láàyè, tó ń lo dáúlà.

Nígbà tó ń fìdí òtítọ́ ọ̀rọ̀ múlẹ̀ nípa ipò tí ọkọ rẹ̀ wà, Joke Silva, tó tún ń jẹ́ Joke Jacobs, tíí ṣe aya òṣèré tíátà náà ní ko ko ko bíi òkúta ni ara ọkọ òun le, ikú kìí pẹtà lójúran. Kò sí ikú kankan lójú rẹ̀.

“Kò sí ohun tó ṣe ọkọ mi, kódà, ó ń palẹ̀ mọ́ lọ́wọ́ báyìí láti ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ọdún kejìdínlọ́gọ́rin tó dé Ilé ayé lóṣù keje tó ń bọ̀, bẹ́ẹ̀ ni ẹnu ya àwọn nígbà tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń bèèrè pé kín ló ṣe ọkọ òun.”

Joke Jacobs wá fi ọkàn àwọn olólùfẹ́ wọn balẹ̀ pé kò sí ewu rárá fún ọkọ òun, pírí lolongo ó jí.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo Ọrẹ …