Home ÀKỌ̀TUN Agbálẹ̀ títì ni ìyá mi, mo sá ńlé bẹ̀rẹ̀ kọ̀ǹdọ́ ni—MC Olúomo
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - June 10, 2020

Agbálẹ̀ títì ni ìyá mi, mo sá ńlé bẹ̀rẹ̀ kọ̀ǹdọ́ ni—MC Olúomo

Agbálẹ̀ títì ni ìyá mi, mo sá ńlé bẹ̀rẹ̀ kọ̀ǹdọ́ ni—MC Olúomo

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé kò sééyan tí wọn yóó bi tí kò níí rí ohun kan àbómí-ìn wí ló bí, àwọn ọ̀rọ̀ àgbọ́ ṣe haa, yàgbàdo ẹnu bí Alága onímọ́tò NURTW nípìńlẹ̀ Èkó, Alhaji Musiliu Ayinde Akinsanya, tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ sí MC Olúomo, ti ń sàlàyé bó ṣe bẹ̀rẹ̀ ìgbé ayé rẹ̀, àti bó ṣe di gbájúmọ́ lọ́jọ́ òní.

MC Oluomo, lásìkò tó ń kópa lórí ètò kàn ló ṣàlàyé pé, ọmọ ọdún méje ni bàbá òun jáde láyé, àtijẹàtimu di ọ̀ràn, iṣẹ́ agbálẹ̀ ojú pópó ni iya òun ń ṣe.

Olúomo fikún un pé “Ọ̀dọ̀ ẹni tó kù ní ìyá fún màmá mi nílù Abeokuta là ń gbé , Màmá mi ń gbálẹ̀ títì ní Èkó, n kò rí ìtọ́jú tó, ni mo ṣe ṣá kúrò nílé lọ́mọ ọdún mẹ́tàlá, tí mo sì ń ṣe kọ̀ǹdọ́ láti Abeokuta wá sí Èkó.”

Olúomo tún sísọ lójú rẹ̀ pé, kò sí ẹnikẹ́ni tó kọ́ òun ní ọkọ̀ wíwà, òun kan ń sún ọkọ̀ síwájú díẹ̀díẹ̀ lórí tọ́ọ̀nù ní gárèjì bíi kọ̀ǹdọ́, ni òun fi mọ ọkọ̀ wà.

Alága ẹgbẹ́ ọlọ́kọ̀ èrò ní Èkó tún fikún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé, inú ìyá òun kò dùn pé òun ń ṣe kọ̀ǹdọ́,tí wọ́n sì fẹ́ mú òun lọ sílé ọmọ aláìgbọràn, tí wọ́n ń pè ní welfare, àmọ́ òun ṣá mọ́ wọn lọ́wọ́, òun sì ń sun ìta.

Ó wá yán an pé, lóòótọ́ ni òun ń sun ìta tàbí inú ọkọ̀ mójú, ṣùgbọ́n òun kò hùwa ọmọ burúkú rí, òun kìí jalè, mu igbó, mu sìgá, ọtí, tàbí ṣe ìpáǹle.

Nígbà tó ń sọ ìdí tí wọ́n ṣe ń pè é ní Olúomo, MC ní “Ojú pópó ni mo gbé dàgbà, a kó ara wa jọ láti dẹ́kun ìwà olè jíjà ní Oshodi, ni ọba mẹrinla ṣe fi mí jẹ oyè Olúomo ní Isọlọ, orúkọ yìí sì ló rò mí, tí mo fi dé ibi gíga.”

Olúomo wá lérí lẹ́ka pé bí Ọlọ́run bá bo òun ní àṣírí, àwọn ọmọ ìta ni òun yóó ràn lọ́wọ́ jùlọ nítorí ọmọ ìta ni òun náà, ìdílé tí kò tòrò ló mú kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn dí ọmọ ìta.”

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí ìbáṣepọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn òṣèré tíátà, Oluomo ní “iyọ̀ ayé àti amúlùúdùn ni àwọn òṣèré tíátà, ìwọ̀nba tí mo lè ṣe, ni mo fi ń ràn wọ́n lọ́wọ́, ohunkóhun tó bá sì wu àwọn èèyàn ni kí wọ́n sọ nípa ìbáṣepọ̀ wa.”

MC Oluomo, ẹni tó ní ẹgbẹ́ awakọ̀ èrò kìí lọ́wọ́ nínú ètò iṣèlú, wá rọ àwọn ọmọ ìta láti máṣe ro ara wọn pin, kí wọ́n máṣe jalè, àmọ́ kí wọ́n lo ọpọlọ wọn láti ṣiṣẹ́, kí wọ́n sì fi ìgbé ayé t’òun ṣe àríkọ́gbọ́n.”

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo Ọrẹ …