Home ÀKỌ̀TUN Sani Abacha, Olórí ológun tí ìjọba rẹ̀ ga ju òfin Orílẹ̀
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - June 9, 2020

Sani Abacha, Olórí ológun tí ìjọba rẹ̀ ga ju òfin Orílẹ̀

Sani Abacha, Olórí ológun tí ìjọba rẹ̀ ga ju òfin Orílẹ̀

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ọba mẹ́wàá, ìgbà mẹ́wàá,ọjọ́ mánigbàgbé ni ọjọ́ kẹjọ oṣù kẹfà ọdún 1998, tí ìròyìn gba Ilẹ̀ kan pé, olórí Ìjọba ológun ní Nàìjíríà, Ọ̀gágun Sani Abacha ti sílẹ̀ bora,gbékuru gàjà, ikú ti kéèémí fintafinta lára akọni.

Ikú òjijì tó pa olórí wa nígbà náà, èyí tó pé ọdún méjìlélógún báyìí, sì ló ń ṣe ọpọ èèyàn ní kàyééfì dàsìkò yìí.

Bí a kò bá níí ṣọ àṣọgbọnu, ìtàn orílẹ̀-èdè Nàìjíríà kò kún, bí orúkọ olóògbé Ọ̀gágun Sani Abacha kò bá hàn látàrí ipa mánigbàgbé tó kó nínú ìṣèjọba Orílẹ̀ yìí.

Ogúnjọ́ oṣù kẹsàn- án ọdún 1943 ni Sani Abacha délé ayé nípìńlẹ̀ Borno, tó sì jẹ́ ẹ̀yà Kanuri àmọ́ ìlú Kano ló ti dàgbà, tó sì lọ sílé ẹ̀kọ́ níbẹ̀.

Ọdún 1963 ni wọ́n gba Sani sáwùjọ iṣẹ́ ológun lẹ́yìn tó kàwé nípa iṣẹ́ ológun nílùú Kaduna lọ́dún 1969 àti nílẹ̀ Gẹẹsi, tó sì jà fitafita nínú ogun abẹ́lé Nàìjíríà.

A kàá pé ọ̀pọ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ ìdìtẹ̀ gbàjọba tó wáyé ní Nàìjíríà ló ń lọ́wọ́ Abacha nínú nígbà tó sì wà ní ipò ‘second lieutenant’ lásán, ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ló ti báwọn kópa nínú ìdìtẹ̀ gbàjọba tó wáyé lósù keje ọdún 1966, tó fi mọ́ èyí tó wáyé lọ́dún 1983, tó gbé Ọ̀gágun Ibrahim Babangida s’órí àga àkóso Orílẹ̀.

Ọdún 1985 tí Ọ̀gágun Babangida sì gba oyè Ààrẹ àti Kọ̀máńdà àwọn ológun ní Nàìjíríà, ọdún náà ni Abacha gba oyè olórí Iléeṣẹ́ ọmọ-ogun orí ilẹ̀, tó sì tún di Mínísítà fétò ààbò lọ́dún 1990.

Lẹ́yìn tí Babangida da ìbò ọjọ́ Kejìlá oṣù kẹfà ọdún 1993 nù, tí gbogbo àgbáyé gbà pé olóògbé Moshood Abiola lo jawe olubori ninu rẹ, ni rògbòdìyàn gbòde, èyí tó mú kí Babangida yẹ̀bá lórí àlééfà, tí wọ́n sì fi Ernest Sonekan jẹ Ààrẹ fìdí hẹẹ́ Orílẹ̀ yìí lásìkò náà.

Àmọ́ ọjọ́ Kẹtàdínlógún oṣù Kọkànlá ọdún 1993 ni Abacha yẹ àga mọ́ Sonekan nídìí, t’óun gan-an sì di Ààrẹ ológun ni Nàìjíríà.

Díẹ̀ lára ìsẹ̀lẹ̀ mánigbàgbè tí Abacha ṣe lórí oyè
Ó yẹ kí á mẹ́nuba díẹ̀ lára bí Ọ̀gágun ọ̀ún ṣe lo sáà pẹ̀lú àwọn àṣọ̀ǹgbè rẹ̀.

Oṣù kẹsàn-án ọdún 1994 ni Abacha kéde pé ìjọba òun ga ju àṣẹ ilé ẹjọ́ lọ Abacha fagilé òfin ológun 691 t’ọdún 1993, tó sì gbé òfin ológun mìíràn kalẹ̀ tó fún un ní agbára tó ga jùlọ bíi apàṣẹ wàhá, tó sì le ti ẹnikẹ́ni mọ́lé fún oṣù mẹ́ta láì gbé e lọ sílé ẹjọ́ .

Abacha sọ MKO Abiola sí ẹ̀wọ̀n fún ẹ̀sùn ìdìtẹ̀ gbàjọba torí pé Abiola pe ara rẹ̀ ní Ààrẹ Nàìjíríà, tó sì fìyà jẹ ẹ́ títí tí Abiola fi gbẹ́mì-ín mì.

Ó tún sọ Olóyè Oluṣẹgun Ọbasanjọ, Shehu Musa Yar’adua, Ọladipupọ Diya àti àwọn èèkàn
ìlú mìíràn sí ẹ̀wọ̀n lórí ẹ̀sùn ìgbìdánwò ìdìtẹ̀ gbàjọba.

Abacha, láti ipasẹ̀ Al Mustafa fi ọwọ́ líle darí Nàìjíríà, ìṣẹ̀lẹ̀ àdó olóró yínyìn gba ìlú kan, ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ ẹgbẹ̀ ajàfẹ̀tọ̀ọ́ ìlú àti ẹgbẹ́ tó n jà fún ìfẹsẹ̀múlẹ̀ ìjọba alágbádá NADECO, di èrò ẹ̀wọ̀n bẹ́ẹ̀ làwọn mìíràn fi ìlú sílẹ̀.

L’ọ́dún 1997, Abacha ṣe àfikún owó tí Orílẹ̀ ń fi pamọ́ sílẹ̀ òkèèrè láti $494m tó wà l’ọ́dún 1993 sí $9.6bn, tí àdínkù sì bá gbèsè tí Orílẹ̀ jẹ láti $36bn sí $27bn .

Ìwà àjẹbánu rẹ́sẹ̀ walẹ̀ tilé toko lásìkò ìṣèjọba Abacha, tí òun fúnra rẹ̀ sì kó òp̣ọ̀lọpọ̀ owó Orílẹ̀ pamọ́ fúnra rẹ̀ níi òkè òkun, táwọn aya, ọmọ, ọ̀rẹ́ àti alábàásisẹ́pọ̀ rẹ̀ náà sì ń kó owó ìlú pẹ̀lú ìrọ̀rùn.

Akitiyan Ìjọba àpapọ̀ mú kí Orílẹ̀ yìí rí díẹ̀ nínú owó náà tó wà lókè okùn gbà padà léyọléyọ lẹ́yìn tíkú bó ó lásìírí.
Abacha sọ ẹkùn tó wà ní Nàìjíríà di mẹ́fà, tó sì tún dá ìpínlẹ̀ tuntun míràn sílẹ̀.

Ìjọba Sani Abacha ló tíì kanjúko jùlọ nínú ìwà títẹ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn lójú mọ́lẹ̀, tó sì pàṣẹ kí wọ́n yẹgi fún Ken Saro Wiwa àtàwọn Ògònì márùn-ún míràn, kódà, ó ṣe ìdájọ́ Wole Soyinka láì sí nílé .

Abacha kó ipa mánigbàgbé sí ogun tó wáyé ní Liberia, tó sì kó àwọn ọmọ ogun apẹ̀tù-sááwọ̀ ránṣẹ́.

Abacha ṣe àgbékalẹ̀ ètò ìpadàbọ̀ sí ètò òsèlú alágbádá, tí òun náà sì díje láti gbégbá ìbò Ààrẹ Alágbádá , àmọ́ ọjọ́ kẹjọ oṣù kẹfà ọdún 1998 ni ikú pa Sani Abacha nílé ìjọba Aso Rock, tí wọ́n sì lọ sin ín sílé rẹ̀ nílùú Kano.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Adédoyin ṣépè fáwọn oníròyìn nílé ẹjọ́

Adédoyin ṣépè fáwọn oníròyìn nílé ẹjọ́ Ọrẹ Òtítọ́jù Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fáwọn oníròyìn láàárọ̀…