Home ÀKỌ̀TUN Ọkùnrin ọ̀mùtí náà fipá bámi ló pọ̀ látojú orun -Arúgbó pẹ̀lú omijé
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - June 6, 2020

Ọkùnrin ọ̀mùtí náà fipá bámi ló pọ̀ látojú orun -Arúgbó pẹ̀lú omijé

Ọkùnrin ọ̀mùtí náà fipá bámi ló pọ̀ látojú orun -Arúgbó pẹ̀lú omijé

Fẹ́mi Akínṣọlá

A kìí gbélé ẹni ká fọrùn rọ́ lẹ̀yin àgbà wí. Bẹ́ẹ̀ ni kò sééyan tó gbàdúrà kó tojú oorun dójú ikú. À mọ́ Ọlọ́run lo Aládùgbóò ìyá arúgbó yìí fún un lọ́jọ́ tí bìlìísì bí èèyàn kan já wọlé ìyá onílé kan tó n gbé ní Ijoko nípìńlẹ̀ Ògùn tí awakọ̀ akẹ́rù kan tó ti mu ọtí yó, ṣe fipá bá a lòpọ̀.

Nígbà tó ń bá akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀, ìyá arúgbó náà, tí a fi orúkọ bò láàṣírí ní, kò sí ẹnikẹ́ni nínú ilé, gbogbo ayálágbé òun ló ti jáde lọ, wọn kò sì tíì wọlé padà, tí ọkùnrin tó mutí yó náà fi fi tipá wọnú yàrá òun.

“Aládùgbóò mi tí mo mọ̀ ni ọkùnrin, ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n náà, ó fi tipá-tipá wọ yàrá mi lásìkò tó mu ọtí yó ní aago mọ́kànlá alẹ́, ó bò mí ní ẹnu, kí n má baà pariwo, ó sì fi ipá bá mi ní àjọṣepọ̀.”

“Mo jà fita-fita àmọ́ apá mi kò ká a, ó ṣe nǹkan tó fẹ́ ṣe, nígbà tó yá, mo ráyé pariwo síta, àwọn aládùgbóò dé, tí wọ́n sì kó ẹgba bò ó lẹ́yìn, kó tó fi mí sílẹ̀.”

Màmá àgbà ní wọ́n ti fi ìṣẹ̀lẹ̀ yìí tó àgọ́ ọlọ́pàá tó wà ní Àgbàdo létí, táwọn ọlọ́pàá sì ti mú afurasí ọ̀hún, bákan náà ni wọ́n bá aṣọ àti iná tọ́ọ̀sì tó fi sílẹ̀ ní yàrá ìyá àgbà náà.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Àwọn wọ̀nyí ti kékeré dèrò ẹ̀wọ̀n, jìbìtì orí ayélujára ló kó bá wọn

Àwọn wọ̀nyí ti kékeré dèrò ẹ̀wọ̀n, jìbìtì orí ayélujára ló kó bá wọn Ọrẹ Òtítọ́jù Àwọn ló …