Home ÀKỌ̀TUN Kété tí wọ́n bá ṣí iléẹ̀kọ́ padà ní ìdánwò WASSCE yóò bẹ̀rẹ̀…Àjọ WAEC
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - June 6, 2020

Kété tí wọ́n bá ṣí iléẹ̀kọ́ padà ní ìdánwò WASSCE yóò bẹ̀rẹ̀…Àjọ WAEC

Kété tí wọ́n bá ṣí iléẹ̀kọ́ padà ní ìdánwò WASSCE yóò bẹ̀rẹ̀…Àjọ WAEC

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ìgbà lonígbà ń kà, àkókò ò wojú ẹnikẹ́ni àyàfi èèyàn tó bá setán àti ṣàmúló rẹ̀ lójú ọjọ́.
Bí a bá wo ọṣẹ́ tí àrùn apinni léèmí Kòrónáfairọ̀ọ̀sì yìí ṣe lẹ́ka gbogbo, a ó ri pé kìí ṣe wàsá, abala ètò ẹ̀kọ́ ní ìròyìn tọ̀tẹ̀ yìí gbérù, níbi tí Àjọ tó ń ṣe kòkàárí ìdánwò àṣekágbá ní ilé ẹ̀kọ́ girama, WAEC ti ṣàlàyé pé òun ti setán báyìí láti ṣètò ìdánwò fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ oníwèé mẹ́wàá l’órílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Àjọ náà ní ohun tó wà láàrin àjọ náà àti ṣíṣe ìdánwò fáwọn akẹ́kọ́ọ̀ oníwèé mẹ́wàá lọ́dún yìí ni ìlànà tí ìjọba bá gbé kalẹ̀ àti ṣíṣí àwọn iléèwé padà.

Ní ọjọ́ ajé ni ìgbìmọ̀ amúṣẹ́yá tí Ìjọba àpapọ̀ gbé kalẹ̀ lórí àrùn apinni léèmí Kòrónáfairọ̀ọ̀sì lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà, PTF ṣàlàyé pé àwọn iléèwé àti iléeṣẹ́ ètò ẹkọ ní jọba àpapọ̀ gbọdọ̀ jókòó láti fẹnukò lórí ìlànà tí ètò ẹ̀kọ́ yóó gbà bí wọn yóó bá ṣí ilé ẹ̀kọ́ padà; paàpá fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ońdànńwò àṣejáde bíi WAEC, NECO àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Nígba tí alukoro àjọ ońdànńwò àṣekágbá girama, WAEC, Ọ̀gbẹ́ni Damian bá akọròyìn sọ̀rọ̀, ó ní ohun tí àwọn ń retí báyìí ni àwọn ìlànà tí Ìjọba àpapọ̀ àtàwọn Ìjọba ìpínlẹ̀ bá fẹnukò lé lórí.

Ó fi kún un pé bí àwọn ilé ẹ̀kọ́ bá leè di ṣíṣí padà, àáyá bẹ́ẹ́ lẹ̀ ,o bẹ́ s’áré ni fún àwọn nítorí àwọn setán láti ṣe ìdánwò náà ní kété tí wọ́n bá ti rí ìlànà gbà láti ọdọ Ìjọba lórí ọ̀nà tí ètò pípadà sí ilé ẹ̀kọ́ yóó gbà báyìí.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu

Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu Ọrẹ Òtítọ́jù Olùdíje fún i…